Wọn ba oku tọkọ-tiyawo ninu ile, awọn mọlẹbi lọrọ naa ki i ṣe oju lasan

Monisọla Saka

Inu ibanujẹ nla ni awọn mọlẹbi tọkọ tiyawo kan, Kẹhinde Ẹgbẹyi ati Bukọla Ẹgbẹyi wa bayii. Eyi ko sẹyin bi wọn ṣe ba oku tọkọ-tiyawo naa ninu ile wọn to wa ni Oke-Erinja, Ilaro-Owode, Yewa, nipinlẹ Ogun loru ọjọ Aje, Mọnde moju.

Gẹgẹ bi iweeroyin Punch ṣe sọ, wọn ni ko sohun to ṣe Kẹhinde ati iyawo rẹ tẹlẹ. A gbọ pe oun pẹlu awọn ti wọn jọ n gbele pẹlu ọkunrin kan ti wọn n pe ni Joel to jẹ ẹgbọn Kẹhinde ti wọn n gbele rẹ ni wọn jọ wa ninu ile lọjọ naa ti wọn n wo tẹlifiṣan, ti gbogbo wọn si ṣere ṣawada ko too di pe onikaluku wọn lọọ sun.

Afi bo ṣe di aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti awọn araale yooku dide, ti wọn si reti pe ki Kẹhinde ati iyawo rẹ naa dide ki wọn le gba oko lọ lati lọọ ṣiṣẹ bii iṣe wọn, ṣugbọn ti ẹnikẹni ko gburoo wọn.

Eyi lo mu ki awọn araale bẹrẹ si i pe wọn, ṣugbọn ti wọn ko gburoo wọn. Nigba ti ọrọ naa fẹẹ kọja bi wọn ṣe ro o ni wọn ba fi ipa ja ilẹkun yara wọn. Kayeefi lo si jẹ pẹlu bi wọn ṣe ba tọkọ-tiyawo naa ti wọn ko le mira mọ lori bẹẹdi ti ẹjẹ n yọ nimu Kẹhinde to jẹ ọkọ, ti kinni funfun bii ifoofo si n yọ nimu iyawo naa.

 Ninu alaye ti ọkan ninu awọn tọrọ naa ṣoju wọn ṣe akọroyin Punch lo ti sọ pe, ‘‘Joel, Kẹhinde ati iyawo rẹ pẹlu awọn ọrẹ wa mi-in lo jọ n wo tẹlifiṣan ninu palọ. Lẹyin ti wọn wo ere naa tan, onikaluku gba inu yara rẹ lọ lalẹ ọjọ naa. Ṣugbọn nigba to di aarọ ti onikaluku mura lati maa lọ soko, a ko gburoo Kẹhinde ati iyawo rẹ, la ba gbiyanju lati kan ilẹkun yara wọn, ṣugbọn ko sẹni to dahun.  Nigba ti a kanlẹkun titi ti wọn ko dahun la fi ipa ja ilẹkun yara wọn. Iyalẹnu lo si jẹ pe oku awọn mejeeji la ba lori bẹẹdi. Niṣe ni ẹjẹ n jade nimu Kẹhinde to jẹ ọkọ, bii ifoofo si n jade lẹnu iyawo rẹ’’.

Nigba to n ṣalaye ohun to le ṣokunfa iku wọnpẹlu bi aọn kan ṣe n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ eefin jẹnẹretọ lo pa awọn eeyan naa, ọkunrin yii sọ pe ki i ṣe bẹẹ raa. O ni ko si jẹnẹretọ ninu ile naa, bẹẹ ni ko si si ni adugbo ti awọn eeyan naa sun si.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Joel to jẹ ẹgbọn Kẹhinde ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe gbogbo awọn lawọn mọ pe iṣẹlẹ to sẹlẹ si Kẹhinde ati iyawo rẹ naa ki i ṣe oju lasan, sibẹ, awọn ti fi gbogbo rẹ silẹ fun Ọlọrun. Eyi lo mu ki wọn kọ fun awọn ọlọpaa ti wọn fẹẹ gbe oku tọkọ-tiyawo yii lọ fun ayẹwo pe ki wọn ma ṣeyọnu, wọn ni awọn ti gba f’Ọlọrun.

ALAROYE gbọ pe wọn ti sin okun tọkọ tiyawo naa.

 

Leave a Reply