Wọn ba ọmọ oṣu meje lẹyin iya ẹ lọjọ keji tawọn agbebọn ti yinbọn pa a

Monisọla Saka

Oriyọmi, Ikudaisi ati ẹni Ọlọrun ko pa, lo yẹ ki wọn maa pe ọmọdekunrin ọmọ oṣu meje kan to n jẹ Habibu, pẹlu bi wọn ṣe ba ọmọ naa to n sun fọnfọn lẹyin mama ẹ ti wọn ti yinbọn pa lati bii wakati mẹrinlelogun.

Pẹlu bo ṣe jẹ pe ọjọ keji ti wọn ti pa iya ẹ ni wọn ri i, ko si si nnkan kan to ṣe ọmọ naa, ẹyin ti mama ẹ pọn ọn si naa lo wa to ti n sun jẹẹjẹ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Trust ṣe sọ, ọjọ ọdun Ileya ku ọla, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lawọn agbebọn kan ṣoro, lẹyin ti wọn di oju ọna Pandogari si Allawa, to wa nijọba ibilẹ Shiroro, nipinlẹ Niger, pa, ti wọn si n da awọn ọkọ duro loju ọna.

Eeyan mẹfa ni wọn ni awọn olubi ẹda naa yinbọn pa, lara wọn ni akẹkọọ-binrin kan, Hauwa Aliyu, ti wọn lo jẹ akẹkọọ ọlọdun karun-un nileewe girama Maryam Babangida Girls’ Science College, Minna, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Niger, ati iya ọmọdekunrin ti wọn ri laaye ọhun.

Gbogbo awọn ti wọn ri ọmọ naa lẹyin tawọn fijilante lọọ palẹ oku awọn eeyan mẹfẹẹfa ti wọn pa mọ, ti wọn si ba ọmọ naa to n sun oorun ẹ lọ, ni wọn n ṣe haa-hin, ti wọn si n sọ pe Ọlọrun ṣi n ṣiṣẹ iyanu, ati pe aanu Ọlọrun lo mu kọmọ naa ṣi wa di igba ti wọn ri i yẹn.

Ẹni to jẹ olori ẹgbẹ awọn ọdọ Lakpma, Jibril Allawa, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe, “Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, niṣẹlẹ laabi ọhun waye, ẹmi mẹfa lo si lọ si i. Nigba ti Maryam pe wa pe oun fẹẹ wale fun ọdun Ileya, a ni ko ma ṣeyọnu, ko duro ṣọdun nileewe, amọ o taku pe oun fẹẹ wale waa ba wa ṣọdun ni. Bo ṣe di pe awọn agbebọn da wọn duro, ti wọn da ẹmi ẹ legbodo niyi”.

O tẹsiwaju pe yatọ si ọmọ oṣu meje ti wọn ri yii, ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan naa jajabọ lọwọ iku ojiji naa, o ni aya ni ibọn ti ba a, ṣugbọn o ribi sare kuro lagbegbe ibẹ, nibi to ti n rapala latari oju ọgbẹ ibọn to ti mu un lawọn eeyan ti ri i, wọn si ti gbe e lọ sile iwosan, nibi to ti n gba itọju lọwọ.

Leave a Reply