Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lori ẹsun idigunjale, adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Ileṣa ti dajọ iku fun Ṣọla Emorua.
Ṣọla, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ni wọn fẹsun idigunjale ati igbimọ-pọ huwa buburu kan. Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 2018, ni wọn kọkọ ṣafihan rẹ ni kootu.
Agbẹjọro lati ileeṣẹ eto-idajọ nipinlẹ Ọṣun, Motọlani Ṣokẹfun, salaye pe ọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun 2015, ni olujẹjọ huwa naa lagbegbe Ayọruntọ, loju-ọna Ilesa si Akurẹ, niluu Oṣu.
O sọ pe aago marun-un aabọ irọlẹ ni Ṣọla atawọn ẹgbẹ rẹ ko ibọn ati ada, ti wọn si digun ja awakọ tirela karosin-in-ni kan to ni nọmba XV 298 APP, Ismaila Azeez.
Ṣokẹfun sọ siwaju pe Ṣọla nikan ni Azeez da mọ laarin awọn adigunjale naa. O pe ẹlẹrii mẹta, o si fi ọpọlọpọ nnkan ẹri silẹ funle-ẹjọ.
Agbẹjọro fun olujẹjọ, Kehinde Aworele, sọ fun kootu pe Ṣọla ti sọ laimọye igba pe oun ko ba ẹnikẹni sọ nnkan ti awọn ọlọpaa gbe siwaju ile-ẹjọ gẹgẹ bii ọrọ ti wọn ni oun sọ.
Ṣugbọn Onidaajọ Isiaka Adeleke ṣalaye pe olujẹjọ jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an, nitori naa, o paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun un titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.