Wọn dajọ iku fun Solomon atawọn ọrẹ ẹ, ọga ṣọja ni wọn pa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori ti wọn pa ọga soja kan, Kọnẹẹli Anthony Okeyin, nipakupa, ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ, ti dajọ iku fun awọn mẹta kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun (24), oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.

Awọn ọdaran ọhun: Agada Solomon, Taiwo Adeniyi, ati Bibisoye Kẹhinde, ni CP Ayọdele Ṣonubi, ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ gbe lọ si kootu lẹyin ti wọn gbimọ-pọ pa ọga ṣọja naa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Ọgagun Okeyin, ti wọn pa nipakupa yii lo jẹ oludari ileewe Nigeria Army Secondary School, ileewe awọn ọmọ ologun, to wa laduugbo Apata, m’Ibadan.

Yatọ si ẹsun ipaniyan, wọn tun fi ẹsun idigunjale kan awọn ọdaran naa, ẹwọn ọdun mẹrinla, mẹrinla si l’Onidaajọ Ezekiel Ajayi, ti i ṣe adajọ kootu ọhun sọ wọn si lori ẹsun keji yii.

Lọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun 2016, ti wọn pa ọkunrin ẹni ọdun mejilelaaadọta naa ni wọn tun digun ja a lole owo ati ẹrọ ibanisọrọ rẹ.

Ninu awijare ẹ niwaju adajọ, Amofin K.K. Ọlọṣọ, to ṣoju agbẹjọro olupẹjọ, ṣalaye bi awọn ọdaran naa ṣe lu ọgagun ẹni ọdun mejilelaaadọta (52) naa titi ti ẹmi ẹ fi bọ.

O ni bakan naa ni wọn ja a lole ẹrọ ibanisọrọ pẹlu ẹgbẹrun marundinlaaadọta Naira (₦45,000) rẹ lẹyin ti wọn pa a tan.

Awọn mẹfa gan-an lọwọ awọn agbofinro tẹ lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn awọn mẹta ti wọn lọwọ ninu ipaniyan ati idigunjale ọhun gan-an ni wọn dajọ iku fun.

Ṣugbọn ni ti awọn olujẹjọ mẹta yooku torukọ wọn n jẹ Ewere Andrew, Udobata Oruza-Uzie, ati Ephraim Obi, niṣe ladajọ da wọn silẹ lati maa lọ lalaafia, o ni wọn ko lọwọ ninu ipaniyan ọhun ni tiwọn.

Awọn to jẹbi ẹsun ọdaran ọhun paapaa fẹnu ara wọn jẹwọ pe awọn lawọn pa ọmọ ogun ilẹ yii ọhun, ọwọ eyi to n jẹ Solomon paapaa ni wọn ti ba ẹrọ ibanisọrọ ọgagun naa, oun lo n fi foonu ṣọja yii ṣakọ kiri lẹyin ti wọn pa a tan.

Agbẹjọro awọn ọdaran yii, Amofin F.O. Awonusi, rọ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo awọn onibaaa rẹ, ṣugbọn ẹbẹ naa ko wọ adajọ leti, o ni ẹni to ba ti ipa ida paayan, ipa ida ni wọn gbọdọ pa oun naa, n lo ba sọ awọn mẹtẹẹta sẹwọn ọdun mẹrinla mẹrinla lẹyin to dajọ iku fun wọn tan.

 

Leave a Reply