Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn ọdọ tinu n bi ti dana sun awọn obinrin meji ti wọn fura si gẹgẹ bii ajinigbe niluu Iwo lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe lagbegbe Orieeru, niluu naa, lọwọ ti tẹ awọn iya mejeeji nibi ti wọn ti n rin irin ifura kaakiri.
Bi wọn ṣe mu wọn ni wọn ko wọn lọ si aafin Oluwoo tiluu Iwo, nibẹ ni wọn ti paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ si agọ ọlọpaa.
Ṣugbọn bi wọn ṣe jade ninu aafin ni inu bi awọn ọdọ naa, lẹyin ti wọn na wọn bii kiku bii yiye ni wọn ko taya si wọn lori niwaju Wema Bank to wa loju-ọna Ọja-Alẹ, ti wọn si dana sun wọn.