Faith Adebọla, Eko
Ẹgbẹ awọn olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ jakejado ilẹ wa ti ni alaga tuntun bayii, Ọnarebu Suleiman Abubakar ni wọn ṣẹṣẹ dibo yan sipo ọhun, oun si ni olori ileegbimọ aṣofin ti ipinlẹ Bauchi.
Nibi ipade nla kan ti wọn ṣe ni otẹẹli Reiz Continental to wa lolu ilu ilẹ wa, Abuja, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee ni idiboyan naa ti waye, eyi lo si fopin si saa ọdun meji ti olori ileegbimọ aṣofin Eko, Ọnarebu Mudashiru Ajayi Ọbasa ti fi wa nipo naa.
Wọn tun yan awọn ọmọ igbimọ iṣakoso tuntun fun ẹgbẹ ọhun, lẹyin ti wọn ti tu ile ka, tawọn ọmọ igbimọ iṣakoso to ṣiṣẹ pẹlu alaga ana, Ọbasa, ti pari saa ọdun meji ti ofin ẹgbẹ naa la kalẹ fun wọn. Lara igbimọ iṣakoso tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan ni Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ ti ipinlẹ Ogun, gẹgẹ bii igbakeji alaga fun ẹkun Guusu/Iwọ-Oorun, Ọnarebu Matthew Kọlawọle gẹgẹ bii akapo ẹgbẹ atawọn mi-in.