Adeoye Adewale
Ni bayii, ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP) ti sọ pe awọn ti fofin de alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Ọgbẹni Kayọde Salakọ, atawọn oloye ẹgbẹ mẹfa miiran ninu ẹgbẹ naa. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ko tẹle ofin ati ilana ẹgbẹ naa. Bakan naa ni wọn tun sọ pe wọn n ṣoju meji pẹlu ẹgbẹ, leyii to ta ko ofin ẹgbẹ ọhun patapata.
Alukoro ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Sam Okpala, lo sọrọ ọhun di mimọ niluu Eko l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, nile ẹgbẹ naa to wa niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Lara awọn oloye ẹgbẹ ti wọn fofin de ni: Ọgbẹni Moshood Salvador, to dije dupo sẹnetọ Aarin Gbungbu Eko, Ọgbẹni Mutiu Okunọla, Messrs Theodore pẹlu Ọgbẹni Ọpẹyẹmi Taiwo.
Ọgbẹni Sam Okpala ni ẹgbẹ gbe igbesẹ yii lẹyin ti abọ iwadii igbimọ kan ti wọn gbe kalẹ jabọ lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu to kọja yii, pe gbogbo awọn oloye ẹgbẹ naa ko bọwọ rara fun ofin ẹgbẹ, ati pe ipa buruku to ko ipalara nla ba ẹgbẹ ni wọn ko lakooko ibo to waye gbẹyin niluu Eko.
Okpala ni, ‘Lẹyin ti igbimọ oluwadii jabọ iwadii rẹ la too mọ pe gbogbo awọn agba ẹgbẹ gbogbo ta a ti fofin de bayii lo jẹ pe ipa buruku ni wọn ko, to si ṣakoba nla gbaa fun ẹgbẹ wa. Ẹri wa pe ṣe ni wọn n ṣoju meji pẹlu ẹgbẹ, eyi si wa lara awọn ohun to fa a ti ẹgbẹ wa ko ṣe rọwo mu rara lawọn ibi kan ninu ibo gomina to pari tan yii niluu Eko. Ofin egbẹ ko faaye gba pe ki eeyan, tabi ọmọ ẹgbẹ maa ṣoju meji pẹlu ẹgbẹ rara, idi niyi ta a ṣe gbe igbesẹ ta a gbe yii.
‘Ninu awọn mejeeje ti wọn jẹbi ẹsun buruku ti wọn fi kan wọn pe wọn n ṣoju ninu ẹgbẹ, Ọgbẹni Sunbọ Onitiri nikan ṣoṣọ lo tete kọwe silẹ pe oun ko ṣẹgbẹ mọ. A ko le maa gbin ọka ka waa gbe ọmọ aparo sabẹ, ki i ṣe ohun to daa pe ki awọn ẹni ta a gbojule maa ṣe radarada pẹlu ẹgbẹ wa’.
Ni ipari ọrọ rẹ, Okpala dupẹ pupọ lọwọ gbogbo awon ojulowo ọmọ ẹgbẹ LP fun ipa pataki, ati bi wọn ṣe duro gbagbaagba ti ẹgbẹ naa lakooko ibo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, pẹlu ibo gomina to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu to kọja yii.