Monisọla Saka
Ki eku ile gbọ ko sọ fun eyi to wa loko ni bayii o, ki adan si gbọ ko sọ fawọn oobẹ to ba nifẹẹ si, ki owo wọn ma baa wọgbo nibi ti wọn ba ti n sare pe awọn fẹẹ fi orilẹ-ede yii silẹ lọ si Dubai.
Ileeṣẹ to n ri si wiwọle ati jijade awọn eeyan lorilẹ-ede UAE, iyẹn, United Arab Emirates Immigration Authorities, ti kede pe awọn o ni i fun awọn ọmọ ilẹ Naijiria ni fisa mọ, wọn lawọn o si ni i jan awọn ti wọn ti sanwo fisa silẹ tẹlẹ ṣaaju akoko yii lontẹ, bẹẹ ni ko saaye fun idapada owo ti wọn ti san silẹ.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni wọn fọrọ naa lede fun awọn alabaaṣiṣẹ pọ wọn ti wọn wa lorilẹ-ede yii atawọn ileeṣẹ to n ko ni rinrin-ajo lọ soke okun.
Bo tilẹ jẹ pe wọn o sọ idi ti wọn fi gbe igbesẹ naa fun ilẹ wa, ijọba Dubai lawọn ti daṣẹ duro lori gbogbo ọrọ eto irinna silu awọn lati orilẹ-ede Naijiria titi tawọn yoo fi yanju ọrọ to wa laarin ijọba awọn ati tilẹ wa. Wọn ni ikilọ ni ofin tuntun tawọn ṣe yii jẹ fawọn ọmọ ile wa ti wọn n gbero lati lọ si orilẹ-ede naa.
Apa kan ọrọ naa ka bayii pe, “Ẹ sọ fawọn onibaara yin lati tun iwe irinna wọn to lẹyin tọrọ to wa laarin ijọba orilẹ-ede mejeeji ba ti lojutuu”
Owuyẹ lati ileeṣẹ eto irinna oju ofurufu kan ṣalaye pe loootọ lọrọ naa, ati pe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn ti kede rẹ. O ni ijọba ilẹ Dubai ko sọ igba ti wọn yoo tun ṣi ibode wọn fawọn ọmọ Naijiria lati tun le maa wa, ṣugbọn lọwọlọwọ bayii o, gbogbo eto to wa nilẹ ni wọn ti figi gun.
Ṣugbọn aṣoju ileeṣẹ ọkọ oju ofufuru Air Peace, sọ pe awọn ọkọ ofufuru ṣi n na ilẹ Naijiria si Dubai, o kan jẹ pe awọn ti wọn ti niwee irinna tẹlẹ nikan lo wa fun ni.