Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti kede pe awọn ti gbaṣọ lọrun ọga ọlọpaa kan, Insipẹkitọ Adado Mohammed, ti wọn fẹsun iwa ọdaran kan laipẹ yii pe oun pẹlu awọn ọdaran kan ji araalu kan gbe lagbegbe Gwagwalada, niluu Abuja, ti wọn si gba obitibiti owo lọwọ rẹ ko too di pe wọn ju u silẹ fawọn ẹbi rẹ.
Yatọ si ọga ọlọpaa naa ti wọn fi jofin, ileeṣẹ ọlọpaa tun da sẹria nla fawọn ọlọpaa mẹta kan ti wọn ni wọn jẹbi awọn ẹsun iwa palapala ti wọn fi kan wọn. Ijiya awọn yẹn ni pe ṣe ni wọn ja okun apa wọn kuro, ti wọn si da wọn pada sipo ti wọn wa tẹlẹ.
ALAROYE gbọ pe ọga ọlọpaa, Insipẹkitọ Adado Mohammed, ti wọn gbaṣọ lọrun rẹ yii lọọ lẹdi apo pẹlu awọn ikọ ajinigbe kan ti wọn si ji araalu kan, Ọgbẹni Ikechukwu Emmanuel, gbe laduugbo rẹ niluu Abuja. Miliọnu mẹrin ati ẹgbẹrun lọna irinwo Naira ni wọn gba lọwọ awọn ẹbi rẹ ko too di pe wọn ju u silẹ. Yato si eyi, aimọye iṣẹ laabi ni ọga ọlọpaa naa atawọn ẹmẹwaa rẹ ti ṣe laarin ilu ko too di pe ọwọ tẹ wọn laipẹ yii.
Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii, A.C.P Olumuyiwa Adejọbi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, sọ pe o ṣe pataki fawọn lati gbe igbesẹ tawọn gbe naa nitori pe ṣe lawọn ọlọpaa tawọn da sẹria fun fẹẹ ba orukọ daadaa tawọn kan ti fara ṣiṣẹ fun jẹ ni.
O ni, ‘A ko ni i laju wa silẹ ki talubọ ko wọ ọ rara, a ko ni i faaye gba kawọn ọbayejẹ ọlọpaa kan waa ba orukọ daadaa wa jẹ, Lẹyin ta a ṣewadii nipa awọn ẹsun iwa palapala ti wọn fi kan awọn ọlọpaa kan, a ri i pe wọn jẹbi rẹ, a ti da ọga ọlọpaa kan, Insipẹkitọ Adado Mohammed duro lẹnu iṣẹ bayii. Bakan naa la tun da sẹria nla fawọn ọlọpaa mẹta kan, lẹyin ta a ṣewadii daadaa nipa wọn, a ja okun igbega wọn kuro, a da wọn pada sẹyin.
A.C.P Olumuyiwa ni ọga ọlọpaa patapata lorileede yii, I.G Kayọde Ẹgbẹtokun, ti ṣeleri pe iṣakoso oun ko ni i faaye gba iwa palapala laarin ileeṣẹ ọlọpaa. Idi ree tawọn fi n sa gbogbo ipa awọn lati yọ awọn ọbayejẹ ọlọpaa kuro laarin awọn bayii.