Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹni kan ni wọn lo ti pade iku ojiji lasiko tawọn ọmọ ẹyin egungun kan atawọn ọmọ Ibo to n taja lagbegbe Ọjaa’ba, niluu Akurẹ, kọju ija sira wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.
Ẹnikan tiṣẹlẹ yii ṣoju rẹ sọ fun wa pe awọn oniṣowo ọhun ni wọn kọkọ gun ọkan lara awọn ọmọlẹyin egungun naa lọbẹ pa laduugbo Odopetu.
Eyi lo bi awọn ẹgbẹ rẹ ninu ti wọn fi lọọ ya bo ibi tawọn ọmọ Ibo ti n taja niwaju ileetaja Olukayọde, eyi to wa nitosi Ọjaa’ba lati gbẹsan iku ọkan ninu wọn.
Awọn janduku ọhun ni wọn n yinbọn kikan kikan, ti gbogbo eto ọrọ aje ọja agbegbe naa si dorikodo pẹlu bi olukuluku awọn ontaja ṣe fi ọja wọn silẹ, ti won si n sa asala fun ẹmi wọn.
O to bii wakati kan ti wọn fi wa lẹnu rẹ kawọn ọlọpaa too waa tu wọn ka.