Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Bagadaza, nijọba ibilẹ Dukku, nipinlẹ Gombe, ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn ọdaran mẹrin kan to jẹ pe iṣẹ gbaju-ẹ ni wọn maa ṣe fawọn araalu. Wọn tun ni awọn ṣi n wa aafaa kan ti wọn n pe ni Alhaji Auwal, to jẹ pe oun ni olori awọn oniṣẹ ibi naa.
ALAROYE gbọ pe oogun awure pẹlu itaja ni Ọgbẹni Isa Musa kan to n gbe nijọba ibilẹ Bali, nipinlẹ Taraba, wa lọ sọdọ Auwal yii, tọkunrin naa si gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira lọwọ rẹ pe oun yoo ba ṣoogun naa, ti owo yoo si maa pọ si i lọwọ rẹ nigba gbogbo. Ṣugbọn nigba ti Isa ko ri ayipada kankan lẹyin to ti ko gbogbo owo ọwọ rẹ silẹ fun Auwal yii lo ba pada lọ sile rẹ lati lọọ gba owo to ko fun un pada. Ṣugbọn ṣe ni Auwal sọ fun Isa pe ko lọọ ba ọmọọṣẹ oun kan to n jẹ Ibrahim Adamu.
Nigba ti Isa ko ri owo rẹ gba pada lọwọ Auwal, lo lọọ fọrọ naa to wọn leti lagọọ ọlọpaa. Awọn agbofinro lọ sile Auwal lati lọ fọwọ ofin mu, ṣugbọn wọn ko ba a nile, o ti sa lọ.
Mẹrin ninu awọn ọmọ rẹ ni wọn ba gẹge bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Gombe, A.S.P Mahid Abubakar, to n ṣafihan awọn ọdaran naa fawọn oniroyin ṣe ṣalaye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Lara ẹru ofin ti wọn ba lọwo wọn ni: Eegun oku, erupẹ saare, aṣọ funfun atawọn ẹru ofin mi-in ti ko ṣee maa sọ sita. Alukoro ni awọn ti n wa Auwal bayii, ati pe ọwọ yoo tẹ ẹ laipẹ yii. Abubakar ni iṣẹ gbaju-ẹ lawọn eeyan yii maa n ṣe, ṣugbọn ofin ko faaye gba keeyan maa lu araalu ni jibiti owo tabi dukia.
Wọn ni gbara tawọn ba ti pari gbogbọ iwadii awọn tan, lawọn yoo foju gbogbo wọn pata bale-ẹjọ, ki wọn le fimu kata ofin lori ẹsun ti wọn fi kan wọn yii.