Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ojisẹ Ọlọrun kan ti wọn porukọ rẹ ni Pasitọ Solomon Bello ti rẹwọn he latari ẹya ara eeyan ti wọn ka mọ ọn lọwọ niluu Ondo.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, lati ọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni, ọdun ta a wa yii lọwọ ti tẹ pasitọ ẹni ọdun marundinlogoji ọhun ninu ile rẹ to wa laduugbo Morayọ, agbegbe Ayeyẹmi, niluu Ondo.
Awọn ẹya ara ti wọn ba ni ikawọ rẹ lọjọ yii ni ọkan meji to jẹ ti agbalagba, egungun ọrun eeyan ati awọn egungun ara mi-in. Gbogbo nnkan wọnyi ni wọn ba ninu ike funfun nla kan to ko wọn si lati fi joogun kọwọ ofin too pada tẹ ẹ.
Bakan naa la gbọ pe wọn tun ba posi kan lọdọ rẹ pẹlu ọkan-o-jọkan awọn oogun abẹnugọngọ to ko sinu rẹ.
Eyi lo mu ki wọn wọ ọkunrin yii lọ sile-ẹjọ lori ẹsun meji ọtọọtọ, eyi ti i ṣe igbimọ pọ huwa to lodi sofin ati biba ẹya ara eeyan lọwọ rẹ lai ri alaye gidi kan ṣe lori ọna to gba ri wọn.
Ọlọpaa to jẹ agbefọba, Abayọmi Jẹjẹniwa, juwe awọn ẹsun mejeeji bii eyi to lodi labẹ abala ofin igba le mẹtala (213) ati okoo-le lẹẹẹdẹgbẹta din mẹrin (516) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Awọn ẹlẹrii mẹta ni Jẹjẹniwa ko wa sile-ẹjọ lati waa jẹrii ta ko olujẹjọ ọhun lasiko igbẹjọ, bẹẹ lo tun ṣe afihan awọn ẹya ara ti wọn ka mọ ọn lọwọ gẹgẹ bii ẹri lati gbe awọn ẹsun naa lẹsẹ.
Lẹyin eyi lo rọ adajọ lati fiya to tọ jẹ pasitọ naa nitori pe o ti ṣe ohun to lodi labẹ ofin.
Ninu alaye diẹ ti Pasitọ Bello ṣe lasiko ti agbẹjọro rẹ, Amofin S. Aliu, n fi ọrọ wa a lẹnu wo, o ni gbogbo ẹya ara ti wọn ka mọ oun lọwọ ki i ṣe ti eniyan rara, bi ko ṣe ti ẹlẹdẹ.
O ni inu omi ti oun ko awọn ẹya ara naa si lo jẹ ki wọn wu daadaa to fi da bii ẹran eeyan.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ Onidaajọ F. J. Ajiboye, ni ko si ani-ani pe ọkunrin naa jẹbi awọn ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an, o ni idajọ oun ni pe ko lọọ fẹwọn ọdun kan jura lori ẹsun kin-in-ni, nigba ti yoo tun ṣẹwọn ọdun meji gbako fun ẹsun keji ti wọn fi kan an.
Ẹwọn ọdun mẹta naa ni ko faaye owo itanran si fun un.