Wọn ka ibọn ati ọpọlọpọ ọta mọ Destiny lọwọ l’Ọrẹ, o loun ri i he ni

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun oloro, ẹka ti ipinlẹ Ondo, (NDLEA) ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin kan, Destiny Agbaijoh,. lẹyin ti wọn ka ibọn AK-47 kan ati ọpọlọpọ ọta ibọn mọ ọn lọwọ.

Destiny lọwọ tẹ laarin oju-ọna marosẹ Ọrẹ si Okitipupa, lopin ọsẹ to kọja.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin, Alakooso ajọ ọhun nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Kayọde Raji, ni oriṣiiriṣii ọta ibọn to to mọkanlelaaadọrun-un, ibọn mẹrin ati owo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ojilelọọọdunrun le meje Naira (#347, 000) ni wọn tun ba ni ikawọ afurasi naa lọjọ ti awọn mu un.

O ni lara ohun ti awọn tun ṣakiyesi ni pe ami to wa lara awọn ibọn ti awọn ka mọ ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ọhun lọwọ jọ ti ileeṣẹ ọlọpaa.

Bakan naa lo ni awọn tun ba apo nla kan ninu ọkọ rẹ eyi to ṣee ṣe ki wọn maa fi ko oku tabi ẹya-ara awọn eeyan ti wọn ba pa.

O ni dipo ki ọmọkunrin naa jẹwọ iṣẹ to n ṣe lasiko ti awọn n fọrọ wa a lẹnu wo, ẹbẹ lo ni o n bẹ awọn, to si ni o ṣee ṣe ki oun ku ti oun ba fi le jẹwọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa. O lafurasi ọdaran ọhun tun gbiyanju ati fowo di awọn oṣiṣẹ awọn lẹnu ki wọn le fi i silẹ ko maa lọ, ṣugbọn ti wọn kọ jalẹ lati yọnda rẹ.

Raji ni awọn ko ni i pẹẹ fa ọkunrin naa le awọn agbofinro tọrọ kan lọwọ ni kete ti awọn ba ti pari iwadii ti awọn n ṣe lọwọ.

Ninu ọrọ tirẹ, Destiny ni loootọ ni wọn ba ibọn atawọn ẹru ofin naa ni ikawọ oun, ṣugbọn oun kọ loun ni awọn ẹru naa.

O ni iṣẹ igi gẹdu lila loun n ṣe, ati pe inu igbo kan nitosi ibi iṣẹ oun nipinlẹ Bayelsa, loun ti ri ibọn atawọn ọta naa nibi ti wọn ko wọn pamọ si.

Ipinlẹ Bayelsa ọhun lo ni oun ti n bọ, ti oun si n lọ si ilu oun lagbegbe Agbagba, nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, lọjọ ti wọn mu oun.

Leave a Reply