Wọn lawọn ọdaran bii ọgbọn lo sa kuro ni ahamọ SARS, lawọn ọlọpaa ba ni irọ ni  

Olajide Kazeem

Awọn ẹni afurasi bii ọgbọn ni wọn sọ pe wọn ti sa kuro ni atimọle SARS to wa n’Ikẹja, l’Ekoo.

Oriṣiiriṣi esun ọdaran bii idigunjale, ijinigbe ati ipaniyan ni wọn sọ pe o gbe wọn debẹ, ti wọn si n ṣewadii wọn lọwọ ki iwọde tako SARS too bẹrẹ.

Anfaani wahala to de ba awọn SARS yii ni wọn sọ pe awọn janduku ọhun lo, ti bii ọgbọn ninu wọn si ti sa mọ awọn  agbofinro lọwọ bayii.

Ọkan ninu awọn afurasi yii ni wọn sọ pe o fọgbọn tan ọlọpaa to n ṣọ wọn wọle, to lu u  daadaa.

Ẁọn ni lẹyin ti ẹni ti wọn kọlu yii ko le ṣe ohunkohun mọ ni wọn yọ foonu alagbeeka ẹ ati kaadi to fi n gba owo lori ẹrọ ATM, ti awọn ọdaran naa si bẹ sita, ti kaluku wọn fẹsẹ fẹ ẹ.

Ni kete tiṣẹlẹ ọhun waye lawọn ̀ọlọpaa ti kọkọ sọ pe ko si ootọ ninu  pe ̀ọdaran bii ọgọrin lo sa latimọle awọn SARS n’Ikẹja.

Ṣugbọn ẹnikan to ni kawọn oniroyin forukọ bo oun laṣiiri sọ pe o fẹẹ to ọgbọn eeyan to sa mọ awọn lọwọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ekoo, Olumuyiwa Adejobi, ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu ọrọ ọhun, ati pe niṣe lawọn eeyan kan fẹẹ fi da ijaya silẹ saarin ilu.

Bakan naa lo fi kun un pe ọga ọlọpaa ti paṣẹ ki ọfiisi Ọtẹlẹmuyẹ (CID) maa ṣakoso ọfiisi awọn ẹṣọ SARS to wa n’Ikẹja atawọn ẹka mi-in tọrọ ọhun kan kaakiri Eko, ki wọn si maa mojuto awọn afuarasi to wa lahaamọ nibẹ.

 

Leave a Reply