Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lati alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu kẹsan-an yii, ti awọn kan ti yinbọn pa gende-kunrin kan, Dare, ni Abiọla Way, l’Abẹokuta, lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii nipa iku ojiji naa. Bawọn kan ṣe n sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lo yinbọn pa a lawọn mi-in n sọ pe awọn adigunjale ni.
Dare nikan kọ nibọn ba gẹgẹ ba a ṣe gbọ, bakan naa ni ibọn ba Mudaṣiru Azeez, bo tilẹ jẹ pe oun ko ku lẹsẹkẹsẹ bii ti Dare, sibẹ, ọsibitu loun naa balẹ si, o si n gba itọju lọwọ lasiko ti a n kọ iroyin yii ni.
Ohun ti awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ ni pe awọn kan ti wọn wa lori ọkada ni wọn ṣadeede bẹrẹ si i yinbọn soke ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ fẹẹ lọọ lu.
Wọn ni bi wọn ṣe n yinbọn ọhun soke ni wọn n sare buruku lagbegbe Lẹmẹ, titi to fi de Abiola Way. Wọn ni nibi ti wọn ti n yinbọn ọhun lo ti ba Dare to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣogbo (Nigerian Forestry Service), ẹsẹkẹsẹ lo si dagbere faye.
Asiko yii kan naa ni wọn ni ibọn ba Mudaṣiru Azeez, toun fi dero ileewosan ni tiẹ.
Ko sẹni to ri awọn agbebọn ọhun mu, wọn sa lọ raurau ni.
Yatọ si iku Dare yii, bakan naa ni wọn tun ni awọn kan tun da adugbo ru ni Nawair-ur-deen, l’Abẹokuta kan naa, wọn si pa ẹni kan laaarọ ọjọ Jimọ naa.
Lati fidi awọn iṣẹlẹ yii mulẹ, ati lati mọ bo ṣe jẹ gan-an, ALAROYE kan si Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣugbọn ko da esi atẹjiṣẹ ta a fi ranṣẹ si i pada, bo tilẹ jẹ pe o ka a.