Ijọba ipinlẹ Ekiti ti le Olukọ-agba (Principal) ileewe girama, Methodist Girls High School, Ifaki Ekiti kuro lẹnu iṣẹ o. Wọn ni ko lọọ jokoo sile na ti awọn yoo fi mọ ijiya ti yoo tọ si i gan-an. Ohun to ṣe ni pe ko lọ sileewe ọhun ni ọjọ Isinmi, iyẹn ọjọ Aiku, Sannde ijẹta, bẹẹ ọjọ naa ni Gomina Kayọde Fayẹmi ṣe abẹwo ojiji sibẹ.
Kọmiṣanna eto ẹkọ l’Ekiti, Foluṣọ Daramọla, lo kede ijiya yii funra rẹ, to si paṣẹ pe ki igbakeji olukọ-agba naa nibẹ maa gba iṣe rẹ ṣe lẹsẹkẹsẹ. Eto ti wọn ni wọn ṣe silẹ tẹlẹ ni pe Fayẹmi yoo bẹ awọn ileewe kan wo lati mọ bi awọn ileewe naa ti gbaradi to fun iwọle awọn ọmọ ti wọn fẹe ṣedanwo oniwee mẹwaa nibẹ, ko le foju ara rẹ ri i bi wọn ti tẹ le ofin korona yii to. Ana, ọjo Aje, Mọnde, yii lawọn akẹkọọ naa pada sileewe wọn lati bẹrẹ imurasilẹ fun idanwo aṣejade. Ṣugbọn ijọba ti ṣekilọ pe gbogbo ileewe gbọdọ tẹ le ofin korona, ohun ti Fayẹmi n tori rẹ ṣe abẹwo ojiji kiri ree.
Ileeṣẹ eleto-ẹkọ nibẹ ni awọn ti fi ọrọ ranṣẹ si gbogbo ileewe pe gomina naa yoo maa jade kaakiri. Boya olukọ-agba yii ko waa mọ pe gomina yii le de adugbo awọn ni o, tabi boya nnkan mi-in lo ṣẹlẹ, ohun to sa han ni pe nigba ti Fayẹmi de, ko si oluko-agbba nileewe naa, abẹwo ibẹ ko si ṣee ṣe. Ohun to fa ibinu ree, ni wọn ba da ọga naa duro ko ma de ileewe mọ, titi ti ijọba yoo fi mọ ohun ti wọn yoo ṣe fun un.