Monisọla Saka
Afurasi ole ti wọn lo ji ọkada kan ti pade iku ojiji lọwọ awọn ẹgbẹ ọlọkada lagbegbe Igando, nipinlẹ Eko, laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla ọdun yii. Gẹgẹ bi akọroyin Sahara reporters ṣe sọ, adugbo Ara Junction, loju ọna Agric Road, Ẹgan, lagbegbe Igando, nipinlẹ Eko, ni wọn ni ọkunrin ti wọn lu pa naa ati ẹni keji ẹ ti ṣe ọlọkada kan leṣe, lẹyin naa ni wọn gba ọkada lọwọ ẹ, ti wọn si sa lọ.
Loju-ẹsẹ lawọn ẹgbẹ ọlọkada ti wọn ja lole naa ti tẹle wọn, wọn le wọn titi ti wọn fi ri ọkan ninu awọn ole mejeeji mu, wọn si bẹrẹ si i ko lulu fun ọkunrin naa titi ti ẹmi fi bọ lẹnu ẹ.
Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ sọ pe “Awọn Hausa lu ole kan titi to fi ku lagbegbe Ẹgan, Igando, l’Ekoo. Awọn meji lawọn ole ti wọn lọọ gba ọkada lọwọ ọkunrin Hausa kan laaarọ kutukutu Ọjọbọ, Tọsidee. Lẹyin ti wọn gba a tan ni wọn lu ọkunrin naa ni alubami, ti ko si le gbe apa ati ẹsẹ rẹ mọ. Ọkan ninu wọn lọwọ awọn Mọla yẹn pada tẹ nigba ti wọn le wọn ba, wọn bẹrẹ si i lu u pẹlu igi ati nnkan yoowu tọwọ wọn ba ba titi ti ọkunrin naa fi dagbere faye. Nibi ti wọn lu u pa si naa ni wọn fi oku ẹ si kawọn ọlọpaa to waa gbe e nibi to wa”.
Ẹlomi-in to tun ṣalaye sọ pe, ọkunrin ti wọn fagidi gba ọkada lọwọ ẹ naa pada ku, wọn si ti gbe oku ẹ lọ sileewosan nla ijọba to wa ni Igando.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, fidi ọrọ ọhun mulẹ. O ni wọn ti gbe ẹjọ naa lọ si ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran, (SCID), Yaba, nipinlẹ Eko, fun iwadii to peye.
O ni, “Ninu alaye tawọn eeyan ṣe, wọn ni ole lọkunrin naa, nibi ti wọn ti n lu u layiika ile awọn lo ti dakẹ. Amọ nigba tawọn ọlọpaa maa fi debẹ ki wọn le gbe e lọ sile iwosan, o ti gbẹmii mi”.
Hundenyin waa ṣeleri pe oun yoo wadii bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ gan-an.