Ti ayẹwo ba fi le fidi rẹ mulẹ pe ẹjẹ eeyan ni ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlaaadọta kan, Ganiyu Shina, fi n wẹ leti odo ti wọn ti ri i ni agbegbe Kotopo, nijọba ibilẹ Ọdẹda, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, a jẹ pe ọkunrin naa wọ gau niyẹn.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oguin, Abimbọla Oyeyẹmi, fi ṣọwọ si ALAROYE lo ti ṣalaye pe niṣe ni awọn araadugbo naa ri ọkunrin kan to deede paaki mọto Nissan rẹ ṣẹgbẹẹ odo to wa laduugbo Kotopo, o si mu ọṣẹ ati kan-in-kan-in jade, bẹẹ lo gbe ike omi kan sẹgbẹẹ rẹ. Ṣugbọn si iyalẹnu awọn to n wo o, dipo ki Ganiyu maa fi omi wẹ, ẹjẹ ni ọkunrin naa fi n wẹ.
Eyi jẹ iyalẹnu fun awọn araadugbo naa, ni wọn ba n sare pera wọn ni meji mẹta lati waa wo kayeefi ti wọn ri leti odo ọhun.
Nigba ti ọkunrin naa ri i pe awọn eeyan naa ti fura si ohun ti oun n ṣe, iyẹn ẹjẹ to fi n wẹ lai ṣe Ogun lakaaye to lomi nile to n fẹjẹ wẹ, lo ba fere ge e.
Lasiko to n sa lọ yii lawọn araadugbo sare lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Arẹgbẹ, lati lọọ fi iṣẹlẹ naa to wọn leti. DPO teṣan naa, SP Bunmi Asọgbọn, lo ko awọn eeyan rẹ sodi, ni wọn ba sare lọ sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si ri ọkunrin naa mu de agọ wọn.
Nigba to n sọ nipa idi to fi n fi ẹjẹ wẹ, Ganiyu to n gbe ni Ojule kẹrin, Opopona Ogunji, Ọbantoko, l’Abẹokuta, ṣalaye pe ogun kan lo n yọ oun lẹnu, babalawo ti oun si lọọ ba sọ pe ki oun lọọ fi ẹjẹ wẹ leti odo. Eyi loun n ṣe lọwọ tawọn eeyan fi fura si oun, ti oun si fẹsẹ fẹ ẹ. O fi kun ọrọ rẹ pe ki i ṣe ẹjẹ eeyan loun fi n wẹ o, o ni ẹjẹ maaluu ni.
Ṣa, awọn agbofinro ti gba ẹjẹ to ku ninu ike to fi n wẹ naa, wọn ni awọn yoo gbe e lọ sibi ti wọn ti maa n ṣayẹwo ẹjẹ ni laabu lati mọ boya ẹjẹ maaluu ni ọkunrin yii fi n wẹ loootọ. Ṣugbọn to ba lọọ jẹ ẹjẹ eeyan ni, ọkunrin naa ni alaye pupọ ti yoo ṣe fawọn agbofinro bo ṣe sọ ara rẹ di Ogun lakaaye, to si n fi ẹjẹ eeyan wẹ.