Wọn ni aṣọ ologun lawọn agbebọn to ji ọmọ baba kan naa mẹta gbe n’llọrin wọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn agbebọn kan ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro miiran, ti wọn si wọṣọ ologun ni wọn ya bo agbegbe Aseyọri, Alagbado, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji awọn ọmọ mẹta gbe sa lọ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ni awọn agbebọn naa ya bo ile arakunrin kan ti wọn n pe ni Lukuman, bẹẹ ni wọn n yinbọn soke leralera, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ. Ki awọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti ji awọn ọmọ rẹ ọkunrin mẹta gbe lọ.

Bi wọn ṣe fi ọrọ naa to awọn ẹgbẹ fijilante leti ni wọn dide lẹsẹkẹsẹ, ti wọn si bẹrẹ si i le awọn agbebọn naa lọ sọna ilu Shao, lasiko naa ni wọn ri ọkan ninu awọn ọmọ yii gba lọwọ wọn, ti wọn si gbe meji sa lọ.

Lukman, ni ti ki i baa ṣe awọn fijilante to tete dide, awọn ọmọ oun mẹtẹẹta ni wọn iba gbe lọ. Awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe aṣọ ologun ni gbogbo awọn ajinigbe yii wọ.

Titi ta a fi pari akojopọ iroyin yii, awọn ajinigbe naa ko ti i pe mọlẹbi awọn ọmọ ti wọn ji gbe yii lati beere ohun ti wọn fẹ, bẹẹ ni wọn ko ti i ri awọn ọmọ ọhun.

Awọn olugbe agbegbe naa ti waa rọ Gomina AbdulRazaq, lati tete wa ọna abayọ si iṣoro ijinigbe to n waye lemọlemọ ni agbegbe naa, tori pe laarin ọsẹ kan pere, iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni agbegbe naa ti to mẹrin.

Leave a Reply