Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn gende mẹta yii, Abdul Jelili, Oluwatosin Ọlanrewaju ati Yusuf Ọdẹsanya, lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ bayii. Wọn ni afurasi adigunjale ni wọn, bẹẹ ni wọn si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun l’Abẹokuta.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu kejila yii, lọwọ awọn ọlọpaa ba awọn mẹtẹẹta nibi ayẹyẹ kan tawọn akẹkọọ-jade nileewe Moshood Abiọla Poli n ṣe ni OOPL, niluu Abẹokuta.
Abdul Jẹlili lọwọ kọkọ ba gẹgẹ bii alaye awọn ọlọpaa, wọn ni nigba ti awọn to n ṣọ ẹnu ọna abawọle ibi ti ayẹyẹ naa ti n waye yẹ ara ẹ wo ni wọn ba ibọn ibilẹ danku kan lapo ẹ, ọta ibọn kan si wa ninu ibọn ọhun.
Bi wọn ṣe ri ẹru ofin naa lara rẹ ni wọn mu un, nigba ti CSP Sunday Opebiyi ti i ṣe DPO Kemta si ri i bawọn meji yooku, iyẹn Oluwatosin Ọlanrewaju ati Yusuf Ọdẹsanya, ṣe n fẹsẹ gbalẹ kaakiri nibi ayẹyẹ ọhun, ti wọn fẹẹ fipa wọle sibẹ, o paṣẹ pe ki wọn yẹ ara tiwọn naa wo, nitori irin ti wọn n rin nibi eto naa mu ifura dani.
Eyi lo jẹ kawọn ọlọpaa yẹ awọn meji naa wo pẹlu, nigba naa ni wọn si ba ibọn ilewọ mi-in ninu baagi ti wọn gbe dani, bẹẹ ni ọta ibọn marun-un wa nibẹ pẹlu.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun to fiṣẹlẹ naa sita, ṣalaye pe iwadii fi han pe awọn ọmọ to fẹẹ dọgbọn wọle sibi ayẹyẹ ikẹkọọ-jade yii ki i ṣe ọmọọleewe kankan, bẹẹ ni wọn lọwọ si iwa idigunjale to n waye lẹnu ọjọ mẹta yii l’Abẹokuta atawọn iṣẹlẹ to ni i ṣe pẹlu rogbodiyan awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.
CP Lanre Bankọle, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ti ni ki wọn taari wọn sẹka itọpinpin to lagbara.