Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọjọ Sannde ọsẹ yii, Kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ Ogun, Dokita Tomi Coker, fi atẹjade kan sita lati ṣalaye nipa arun onigbameji, iyẹn kọlẹra to bẹ silẹ lawọn agbegbe kan ni Magboro, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode. Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii kan naa, iroyin gbode pe eeyan mẹẹẹdọgbọn (25) laisan naa ti pa, eyi ti Tomi Coker sọ pe ko ri bẹẹ, o ni irọ gbuu ni.
Laarin awọn ọlọkada atawọn to n ṣa ilẹ kiri ni wọn ni arun naa ti n ṣọṣẹ lawọn agbegbe bii Magboro, Arepo, Akeran, Abule-Oko, Akintọnde ati bẹẹ bẹẹ lọ. Alaga CDS agbegbe naa, Oluwaṣẹgun Ọladoṣu, lo sọ ọ di mimọ pe eeyan mẹẹẹdọgbọn ni aisan naa ti pa lawọn agbegbe yii. O ni ni Kara lasan, awọn Hausa bii mẹẹẹdogun lo ti ba aisan naa rin laarin asiko to bẹ silẹ yii.
Ṣugbọn ijọba ipinlẹ Ogun ni ko si akọsilẹ ohun to jọ onka yii lọdọ awọn, Kọmiṣanaa eto ilera naa ṣalaye pe ko ti i si akọsilẹ iku kankan nipasẹ aisan yii laarin wakati mẹrinlelogun. O ni ko tilẹ si alaaarẹ rẹpẹtẹ ti Kọlẹra naa da gunlẹ lasiko yii, nitori eyi ti ko ba wa ti gba itọju, Ọjọruu ni yoo si gba idasilẹ, ti yoo maa lọ sile rẹ pada, ti yoo kuro ni ọsibitu alabọọde to wa ni Magboro, nibi to ti n gba itọju.
Dokita Coker ṣalaye pe lati inu igbọnsẹ ni kokoro to n fa aisan yii ti n wa, awọn ti wọn n ṣegbọnsẹ tan ti wọn ki i fọwọ, ti wọn yoo fi ọwọ naa jẹun bẹẹ ko le ṣai lugbadi aisan bii eyi. O tẹsiwaju pe ṣiṣẹ igbọnsẹ kaakiri ilẹ lai tẹle ofin imọtoto naa le fa ajakalẹ arun yii. Lati ṣẹgun ẹ ṣa, o ni ijọba ti ṣeto aaye itọju sagbegbe naa fawọn to ba ṣẹlẹ si, awọn si ti ba awọn ọba ati baalẹ ibẹ sọrọ lati maa la awọn eeyan wọn lọye lori imọtoto.
Lati mọ iye eeyan ti kinni ọhun ti ti si koto, Dokita Coker ni iwadii ṣi n tẹsiwaju.
Ni ibẹrẹ pẹpẹ ajakalẹ arun yii, Dokita Coker sọ pe iwadii fi han pe alejo ni ẹni to ko o de ipinlẹ yii, o ni ẹni naa rin irinajo, nigba to de lo gbe wahala onigbameji de. Ati pe ile igbọnsẹ gbogbogbo (public toilet) ni wọn ti n ko kinni naa to fi n tan kari, atawọn to n ṣegbọnsẹ silẹ kiri laibikita.
O ni ijọba ti ti ile igbọnsẹ gbogbogbo ti wọn fura si pe arun naa ti n tan kalẹ pa, aaye itọju si ti wa fawọn ti kinni naa ba ṣi n ṣe.