Faith Adebọla
Ti wọn ba n ṣadura pe k’Ọlọrun ma jẹ ka rin lọjọ tebi n pa ọna, ka ma ba wọn rin irin arinfẹsẹsi, iru ẹ leyi to ṣẹlẹ lafẹmọju Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, nigba ti ijamba ọkọ mẹta kan waye nibudokọ ero to wa ni Ketu, Ikosi, lọna marosẹ to lọ si Ikorodu, ipinlẹ Eko.
Ba a ṣe gbọ, eeyan mẹrin lo dagbere faye lairotẹlẹ ninu iṣẹlẹ ọhun, awọn bii mẹrindinlogun lo si fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii, nigba ti bọọsi gbọgbọrọ LAGBUS, kan n ja ṣooroṣo bọ lati Alapẹrẹ, wọn ni bireeki ọkọ naa ti feeli, tori ko tilẹ fi ami han pe yoo duro rara, niṣe lo sẹri mọ awọn ọkọ akero Varagon ti wọn n ṣọrọ aje idaji lọ ni tiwọn, o si ṣeku pa awọn to fẹẹ wọ mọto atawọn to fẹẹ sọda titi, ẹyin eyi lo lọọ sẹri mọ opo irin ti wọn ri mọlẹ sẹgbẹẹ titi fun patako ipolowo, bi ko ba si si ti opo irin ati ogiri yii ni, niṣe lọkọ naa iba sọda sori awọn ṣọọbu to wa ninu ọja Alapẹrẹ lẹgbẹẹ keji titi ọhun.
Nigba ti ALAROYE debi iṣẹlẹ naa, a ri ipa ẹjẹ awọn to doloogbe atawọn to fara gbọgbẹ, a si ri bọọsi LAGBUS ti wọn loun lo ṣokunfa ijamba naa nibẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ti ko awọn oku atawọn to fara gbọgbẹ lọ, wọn si ti wọ meji ninu awọn ọkọ tiṣẹlẹ yii kan lọ, ṣugbọn LAGBUS ṣi wa nibi to fori ha si.
“Tunde Ọlajimi, to niṣeju oun niṣẹlẹ naa ṣe waye sọ f’ALAROYE pe nnkan bii aago mẹfa ku iṣẹju diẹ loun de ita lati bẹrẹ iṣẹ ounjẹ oojọ oun. O ni obinrin alaboyun kan pe ọlọmọlanke lati ba a gbe ẹru sọda titi, ọlọmọlanke naa ko tete dahun, nibi ti obinrin to diwọ-disẹ sinu yii ti boju wẹyin lati ba ọlọmọlanke sọrọ, ojiji ni ọkọ naa kọ lu wọn, o fọ alaboyun naa lori, niṣe lọpọlọ ẹ fo jade, ẹjẹ si ṣan kaakiri. O pa ọlọmọlanke naa, awọn ero to wa ninu ọkọ ọhun ni lati fọ gilaasi windo ọkọ lati bẹ jade ni.
“Nigba taawọn eeyan yoo fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, dirẹba to wa ọkọ naa ti sa lọ. Oku mẹrin ni wọn gbe kuro nibi iṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe a o le sọ boya ẹlomi-in ku ninu awọn ero bii mẹrindinlogun ti wọn ko lọ sọsibitu.”
SP Benjamin Hundeyin, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni iwadii ti bẹrẹ lori ẹ, awọn si maa wa dẹrẹba ọkọ naa lawaari.