Ọlawale Ajao, Ibadan
Abẹṣẹ-ku-bii-ojo ọmọ Ijẹbu-Igbo to n ṣoju orilẹ-ede yii, Akeem Sadiku, ẹni tọ́pọ̀ eeyan mọ sí Dòdó ti dagbere faye.
Lọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, lo faye silẹ to rọrun alákeji.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lati ọsẹ meji sẹyin lọmọkùnrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) yii ti wa ni UCH, ìyẹn ileewosan ijọba apapọ n’Ibadan.
Iṣẹ abẹ ni wọn ṣe fun un lati ba a yọ ìpákè to n yọ ọ lẹnu lẹgbẹẹ isalẹ ikùn rẹ.
Wọn ti ṣiṣẹ abẹ ọhun láṣeyọrí ko tóo bẹrẹ sí í pariwo ara riro pẹlu ìnira lọjọ Sátidé to kọja.
Awọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ dokita pa gbogbo itu to n bẹ lọpọlọ wọn láti doola ẹmi ọmọkùnrin tó ti di ogo Naijiria yii, ṣugbọn àìsàn la ri wò, ẹnikan kò ri tọlọjọ ṣe.
ALAROYE gbọ pe awọn dokita ba nnkan lubulubu to dà bíi ìgò ti wọn fi ọlọ ata lọ̀ kúnná ninu ikùn abẹ̀ṣẹ́-kù-bí-òjò yii, eyi to fi hàn pé wọn fún ùn ní májèlé jẹ ni.
Ààrẹ igbimọ to n ṣakoso ere ẹṣẹ kikan lorileede yii, Dokita Rafiu Ladipọ, ati Ọgbẹni Ọ̀pálẹ́yẹ Gbenga, ti í ṣe akọwe àjọ to n dari ere ẹṣẹ kikan ni ipinlẹ Ọyọ, bara jẹ gan-an lori iṣẹlẹ yii.
Wọn ṣàpèjúwe iku ọmọkùnrin ayara-bii-aṣa nídìí ẹ̀ṣẹ̀ kíkan yii gẹgẹ bíi àdánù nla fun orileede yii lagbo èrè idaraya, paapaa, labala ẹ̀ṣẹ́ kikan ti ọdọmọde yii yàn láàyò.
Ilana ti Dòdó fi máa n jà ẹṣẹ nígbà ayé ẹ kò yàtọ sí ti agba ọjẹ ẹlẹṣẹẹ agbaye nni, Mike Tyson, ọmọ orilẹ-ede Amẹrika.
Ija mọkanla ni Sadiku ti ja. Ẹẹkan pere ni wọn bori ẹ, o ja ọ̀mì lẹ́ẹ̀kan naa, nigba to bori awọn alatako rẹ̀ lẹẹmẹsan-an ọtọọtọ. Meje ninu awọn ija mẹsan-an paapaa lo jẹ pe wọn ko ti i ba ija debikan to ti lu awọn alatako rẹ lálùbolẹ̀.
Eyi to gbẹyin ninu ija rẹ̀ lo waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣù kejìlá, ọdún 2020, nibi to ti na George Amuzu, akẹgbẹ ẹ lati orilẹ-ede Côte D’Ivoire lálùbolẹ̀ gẹgẹ bíi iṣe ẹ̀ lọpọ ìgbà.
Ọmọ bíbí ìlú Ìjẹ̀bú-Igbó ni wọn pe Sadiku. Laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni wọn sinkú ẹ nilana Musulumi n’Ìjẹ̀bú-Igbó ti í ṣe ilu abinibi ẹ.