Wọn n’Igbakeji Sanwo-Olu ti bura l’Amẹrika tẹlẹ p’oun ki i ṣọmọ Naijiria mọ o

Faith Adebọla

 Agbẹjọro kan to n ṣoju fun ileeṣẹ to n ri si iwọle ati ijade nilẹ Amẹrika, iyẹn US Immigration, Amofin Olubusayọ Faṣidi, ti ṣalaye niwaju igbimọ tiribuna to n gbọ awuyewuye esi idibo nipinlẹ Eko, Lagos State Governorship Election Petition Tribunal, pe Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Dokita Ọbafẹmi Hamzat, ti wa labẹ ibura pe oun ki i ṣe ọmọ orileede Naijiria mọ, wọn lo lọmọ ilẹ Amẹrika loun fẹẹ maa jẹ, o si ti tọwọ bọwe ọhun tipẹ ṣaaju eto idibo to kọja yii.

Nibi igbẹjọ awọn ẹsun ti oludije funpo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebọ Rhodes-Vivour fi kan ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, Gomina Babajide Sanwo-Olu ati Igbakeji rẹ, Ọbafẹmi Hamzat lọrọ ọhun ti waye, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

Fasidi, to yọju sibi igbẹjọ naa gẹgẹ bii ọkan lara awọn ẹlẹrii Rhodes-Vivour tako ijawe olubori Sanwo-Olu, ṣalaye nigba ti Agbẹjọro Rhodes Vivour, Amofin agba Dokita Olumide Ayẹni ni ko sọ ohun to mọ nipa jijẹ ọmọ oniluu Hamzat l’Amẹrika, o ni nitododo, olujẹjọ kẹta yii, iyẹn Hamzat tọwọ bọwee lati jẹ ọmọ orileede Amẹrika, ninu fọọmu 8CFR/337 ati N400, o si ko awọn ẹda fọọmu ọhun kalẹ gẹgẹ bii ‘ẹri maa jẹ mi niṣo’, siwaju awọn adajọ, ki wọn le gba a wọle.

Amọ agbẹjọro Hamzat ati Sanwo-Olu, Amofin agba Bọde Ọlanipẹkun fo dide pe ki tiribuna naa ma gba awọn ẹri naa wọle, o loun yoo maa sọ idi toun fi ta ko o lopin igbẹjọ naa.

Agbẹjọro INEC, Amofin Eric Ogiegor ni o yẹ ki ẹlẹrii Rhodes-Vivour yii mọ pe ko sohun to buru ninu keeyan jẹ ọmọ orileede meji labẹ ofin ilẹ wa, Abilekọ Faṣidi si fesi pe ọrọ keeyan jẹ ọmọ orileede meji labẹ ofin ilẹ Amẹrika ni wọn ni koun waa jẹrii nipa ẹ, oun o mọ nipa eyi ti ofin Naijiria sọ.

Ọlanipẹkun ni ki obinrin naa sọ ọjọ pato ati ibi ti onibaara oun, Hamzat, ti beere lati di ọmọ ilẹ Amẹrika, amọ o fesi pada pe oun ko le tu aṣiri iyẹn tori ofin ilẹ Amẹrika Privacy Act tọdun 1974 ko faaye gba oun lati sọ iru nnkan aṣiri bẹẹ sita.

Agbẹjọro ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni tiẹ, Amofin Norris Quakers beere lọwọ ẹlẹrii yii boya o mọ pe Hamzat ti jẹwọ tẹlẹ pe ọmọ ilẹ Amẹrika tun loun, o loun mọ bẹẹ. N ni Quakers ba yiju si Igbimọ onidaajọ, o ni “Oluwa mi, ofin ni ẹlẹrii yii waa ṣalaye ẹ, ki i ṣe koko ẹsun ti wọn fi kan onibaara mi. Ẹri yii ko wulo lori ẹjọ to wa nilẹ, ẹ da a nu.”

Onidaajọ Arum Ashom, to lewaju igbimọ ẹlẹni mẹta naa, eyi ti Onidaajọ Mikail Abdullahi ati Onidaajọ I. P. Braimoh jẹ ọmọ igbimọ, sọ pe awọn gba awọn ẹri naa wọle, wọn ni kawọn olujẹjọ to ta ko awọn ẹri yii ṣalaye idi ti wọn fi ta ko o to ba ti ya, wọn si sun igbẹjọ to kan si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023.

Ṣaaju ni Amofin agba ayẹni ti ko awọn ẹda esi idibo kan to ṣafihan iyatọ ati aidọgba pẹlu ohun ti ajọ INEC kọ silẹ sori fọọmu EC40A wọn, gbogbo ẹ si ni igbimọ yii gba wọle.

Leave a Reply