Ọlawale Ajao, Ibadan
Nnkan ko ṣẹnuure fun aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja, Sẹnetọ Kọla Balogun, ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC lẹkun idibo Ariwa Ọyọ to waye ninu ọgba UCH, n’Ibadan, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ṣe yẹyẹ ẹ, ti wọn pariwo ole le e lori.
Balogun, ẹni to di Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP, lo dara pọ mọ ẹgbẹ APC ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin, to jijadu lati tun ipo naa du ninu ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ, ṣugbọn ti ọrọ bẹyin yọ fun un ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu rẹ tuntun yii lọjọ Satide to kọja.
Tikẹẹti lati tun dupo yii fun saa keji to padanu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, pẹlu bi gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ṣe gba tikẹẹti ọhun lọwọ ẹ fun Oloye Ọlasunkanmi Joseph Tegbe, lo mu Sẹnetọ Balogun binu fi ẹgbẹ PDP silẹ, to ṣi lọọ tun ipo naa du ninu ẹgbẹ APC.
Amọ ṣaa, niṣe ni sẹnetọ yii tun fidi-rẹmi sọwọ ọmọ gbajugbaja oniṣowo Ibadan nni, Kọlapọ Kọla-Daisi, ninu idibo abẹle yii pẹlu bi onitọhun ṣe ni ibo okoolerugba-o-din-mẹjọ (212) nigba ti Sẹnetọ Balogun to wa nipo yii lọwọlọwọ ni ibo mẹtalelaaadọrun-un (93) pere.
Ṣugbọn ti pe sẹnitọ to jẹ aburo Ọba Lekan Balogun ti i ṣe Olubadan ilẹ Ibadan ko ri tikẹẹti gba nikan kọ nipenija to doju kọ ọ ninu idibo yii, ṣaaju idibo ọhun lawọn ọmọ ẹgbẹ APC, to jọ pe wọn jẹ alatilẹyin Kọla-Daisi, ya lọọ ba a nibi to jokoo si, ti wọn si bẹrẹ si i kigbe ‘Oole! Oole! le e lori, wọn lo fẹẹ ti inu ẹgbẹ PDP waa gba tikẹẹti ninu ẹgbẹ awọn.
Awọn ma-jẹ-o-bajẹ inu ẹgbẹ naa l’Ọlọrun fi koore wahala lọjọ naa pẹlu bi wọn ṣe parọwa fun Sẹnetọ Balogun, ti wọn ko jẹ ko da awọn to n foju ọla ẹ gbolẹ yii lohun, eyi to si ṣee ṣe ko mu ikọlu nla ba aṣofin agba yii.
Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan lorukọ idile Aliwo, ti i ṣe idile Olubadan to wa lori itẹ lọwọlọwọ, Olori Ọlayinka Balogun bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, o ni ikọlu si sẹnetọ naa ko tọwọ ẹlomi-in wa bi ko ṣe latọwọ awọn ọta ilọsiwaju ilu.
O ni iṣẹlẹ ọhun ko ni i da omi tutu ṣọkan sẹnetọ yii ninu iṣẹ idagbasoke ilu gbogbo to n ṣe.