Faith Adebọla, Ogun
Pẹlu ikanra ati ọgbẹ ọkan lawọn eeyan fi n rọjo epe sori awọn ‘oru laa ṣeka’ ẹda ti wọn da ẹmi tọkọ-taya kan, Kẹhinde ati Bukọla Fatinoye, legbodo loru mọju ọjọ ọdun tuntun, ti wọn si tun ji ọmọ wọn, Ọrẹoluwa Fatinoye ati ọmọọdọ wọn gbe sa lọ. Awọn apẹja ni wọn ri oku ọmọ ọhun to lefoo tente soju omi odo Ogun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, iyẹn lẹyin ọjọ kẹta ti ọn ti ji i gbe lọ.
Ọkan ninu awọn apẹja ọhun, Idowu Taiwo, ṣalaye pe: “Lọjọ Mọnde, a gbọ pe awọn olubi ẹda kan ti ju eeyan sinu odo yii, a gbiyanju lati wa a, ṣugbọn a o ri nnkan kan, a o si mọ pato ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Amọ, lafẹmọju yii, nigba ti a n gbaradi fun iṣẹ wa, awọn ọlọpaa waa ba wa, wọn ni ka fi to awọn leti nigbakuugba taa ba ri oku eeyan eyikeyi leti omi.
“Ni nnkan bii aago meje aabọ, ba a ṣe bọ soju agbami la n wo oku eeyan to lefoo tente sapa ọhun yẹn (o naka sibẹ), awa tiẹ ṣi n ṣayẹwo awọn irinṣẹ ta a fi n pẹja lọwọ ninu ọkọ. Bi mo ṣe ri i ni mo bẹ ẹnikan ko ba wa pe nọmba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lati sọ fun un.
Ko pẹ lẹyin naa, awọn ọlọpaa de, a fi oku naa han wọn lẹyin ta a ti yọ ọ jade, awọn mọlẹbi oloogbe naa wa pẹlu, awọn ọlọpaa si gbe oku naa sinu ọkọ wọn,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ fawọn oniroyin lẹyin naa pe awọn ti gbe oku ọhun lọ si mọṣuari lẹyin tawọn mọlẹbi ati ọmọọdọ ti wọn jọ ju wọn somi ti fidi ẹ mulẹ pe Ọrẹoluwa Fatinoye gan-an ni.
O ni ori ko ọmọọdọ naa yọ, tori o ṣalaye fawọn pe ninu ọkọ ayọkẹlẹ tawọn agbanipa naa gbe wa ni wọn ti de awọn lọwọ, ki wọn too ju awọn mejeeji sodo Ogun. O loun ja pitipiti titi, Ọlọrun si ba oun ṣe e ti ọwọ oun kan yọ jade ninu okun ọhun, loun ba luwẹẹ jade. O loun loun ta awọn apẹja lolobo pe wọn ti ju eeyan kan sodo. Wọn ni ọmọọdọ yii ti wa lọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, nibi to ti n ran wọn lọwọ bi wọn n wadii iṣẹlẹ aburu yii.
Tẹ o ba gbagbe, ibi ijọsin adura alaja ọdun, eyi tọpọ awọn ẹlẹsin Kirisitẹni maa n lọọ gba lalẹ ọjọ to kẹyin ninu ọdun si idaji ọjọ ki-in-ni, ọdun tuntun, ni tọkọ-taya Kẹhinde Fatinoye ati Bukọla Fatinoye ti n dari bọ lafẹmọju ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ ki-in-ni, oṣu Ki-in-ni, ọdun 2023 yii. Ko pẹ ti wọn wọle to wa laduugbo GRA Ibara, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, tan lawọn afurasi agbanipa kan wọle tọ wọn, wọn pa wọn nipa ika, lẹyin naa ni wọn si dana sun oku wọn, wọn si ji ọmọ wọn ati ọmọọdọ wọn kan gbe lọ.
Banki apapọ ilẹ wa, Central Bank of Nigeria, ẹka ti Abẹokuta ni baale ile yii ti n ṣiṣẹ, akọwe agba si ni iyawo rẹ ni fasiti ẹkọ nipa iṣẹ agbẹ, iyẹn Federal University of Agriculture, FUNAAB, l’Abẹokuta.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọhun ni wọn ti sinku tọkọ-taya yii lẹyin eto isinku to waye ni ṣọọṣi Christ Anglican to wa n’Iporo-Ake, l’Abẹokuta, itẹkuu ṣọọṣi naa si ni wọn sin wọn si.
Oyeyẹmi ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle funra ẹ lo n ṣe kokaari itọpinpin lori iṣẹlẹ yii, o lawọn ti ri afurasi kan mu, itọpinpin to lọọrin yoo si waye titi tawọn maa fi tuṣu desalẹ ikoko iṣẹlẹ aburu naa.