Adewale adeoye
Ni bayii, ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ti wọn n ri sọrọ ayika, ‘‘Lagos State Environmental Protection Agency’ (LASEPA) ti lọ kaakiri awọn agbegbe nipinlẹ naa lati fọwọ ofin mu awọn ileetaja igbalode, awọn ileejọsin atawọn ileeṣẹ aladaani gbogbo ti wọn n tapa sofin ayika.
Lara awọn agbegbe ti wọn lọ ni Muṣin, Amuwo Ọdọfin, ati Ọkọta Isọlọ, nipinlẹ Eko.
ALAROYE gbọ pe lara awọn ileejọsin atawọn ileeṣẹ aladaani kan ti wọn ti pa ni awọn bii: ’Daily Bakery, The Redeemed Christian Church of God, Gak Universal Allied Limited, Ideal Standard, Franjane Royal Suite, Golden Haven Resort and Suite, Festival Hotel Conference Center and SPA, FS Service Center, Moulin Rouge Ventura ati Olivia mall.
Ọga agba ajọ LASEPA, Dokita Babatunde Ajayi, to fidi iṣelẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, sọ pe ijọba ipinlẹ Eko ko ni i laju rẹ silẹ kawọn ọbayejẹ ẹda gbogbo waa ba alaafia to wa niluu Eko jẹ.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe, ‘‘A ti lọ kaakiri ipinlẹ Eko, a si fọwọ ofin mu awọn aleti lapa kan ti wọn n tapa sofin ayika. Ariwo buruku ni wọn fi n di awọn araalu lọwọ. Igba keji ree ta a maa lọọ ki wọn nilọ, wọn fẹẹ joye alaigbọran ni, awa ko ni i gba fun wọn lae, ilu Eko ki i ṣe ibi ti ẹnikan ti ga ju ofin lọ, ojuṣe gbogbo wa pata ni lati daabo bo ipinlẹ Eko atawọn olugbe ibẹ’’.
Ọga agba naa waa rọ awọn araalu pe ki wọn tete fi to awọn leti bi wọn ba ri araalu kan ti ko bọwọ fun ofin ayika lagbegbe rẹ, kawọn le waa fọwọ ofin mu onitọhun loju-ẹsẹ.