Adewale Adeoye
Awọn agba bọ wọn ni, beeyan ba dakẹ, tara rẹ, a baa dakẹ ni, owe yii gan-an lo ṣe rẹgi ọro agba oṣere tiata nni, Magaret Ọlayinka, ẹni tawọn eeyan mọ si Iya Gbonkan ninu awọn fiimu agbelewo gbogbo lorileede yii. Laipẹ yii ni iya naa pariwo sita pe ki awọn afẹnifẹre, awọn ololufẹ oun ṣiju aanu wo oun, ki wọn fun oun naa ni mọto. Iya yii ni o pẹ ti oun ti n gan mọto kiri, ko si wu oun lati maa ṣẹ bẹẹ mọ, bẹẹ ni agbata oun ko gbe e lati ra mọto funra oun.
Ni bayii Ọlọrun ti gbọ adura oṣere agbalagba yii pẹlu bi awọn kan ṣe kora wọn jọ, ti wọn si dawo jọ fun un lati fi ra mọto naa bayii.
ALAROYE gbọ pe owo to le ni miliọnu marun-un Naira ni wọn ti tu jọ fun mama agba yii. Awọn ololufẹ ẹ nilẹ yii ati loke okun la gbọ pe wọn da owo naa jọ.
Bakan naa ni wọn ni awọn oṣere kọọkan naa wa ninu awọn ti wọn dawo jọ fun un pe koun naa fi ra mọto tiẹ gẹgẹ bii ohun to sọ pe o jẹ ẹdun ọkan foun ninu fidio oniṣeju diẹ kan bayii ti Iya Gbonkan ṣe jade laipẹ yii.
Lara awọn oṣere tiata tawọn paapaa ti nawọ owo si Iya Gbonkan ni awọn bii: Abẹni Agbọn ati Tamọ-Tiye, owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ni awọn mejeeji yii fi ṣọwọ si i pe ko fi kun owo mọto to fẹ naa.
Ohun ti akọroyin wa gbọ nipa bi owo mọto ti Iya Gbonkan fẹẹ ra ṣe tete ṣara jọ bayii ni pe pasitọ kan niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ni Ọlọrun n lo fun eto ikowojọ naa bayii. Wọn ni oun lo bẹrẹ si i pe awọn eeyan nilẹ yii ati loke okun pe ki wọn dide iranlọwọ owo si Iya Gbonkan lati fi ba a ra mọto to n dun un lọkan lori akanti kan ti pasitọ naa fi sita pe ki wọn maa dawọ ọhun jọ sinu rẹ bayii.
Ni kukuru, wọn ti gba to miliọnu marun-un Naira bẹẹ ni yoo tun lo iyooku ninu owo naa lati fi pari ile rẹ to n kọ lọwọ.
Lori ẹbun owo tawọn ololufẹ Iya Gbonkan yii ti n da jọ fun un lo mu ki iya naa femi imoore han sawọn ololufẹ rẹ gbogbo nile ati lẹyin odi, to si n gbadura fun wọn gbogbo adawọle wọn pata ni yoo maa yọri sibi to daa bayii.
Iya Gbonkan ni, ‘ Mo ṣẹṣẹ gba pe loootọ, eeyan laṣọ iyi mi ni o, mo mọ pe mi o lagbara lati da ṣe nnkan kan bayii rara, ẹyin gan-an ni eemi ti mo fi n mi bayii, ki Ọlọrun Ọba ma ṣe ba ajọṣẹpọ to wa laarin gbogbo wa jẹ, inu mi dun gidi lati ri i pe mo beere fun iranlọwọ owo mọto, ẹ si dide iranlọwọ naa fun mi ni kia bayii, lai fakooko ṣofo rara. Ẹ ṣeun, mo dupẹ gidi lọwọ yin gbogbo. Ẹ ko ni i mọ ikoro gbẹyin nile aye yin, bẹẹ ti ṣe ṣoore nla yii fun mi’.