Faith Adebọla, Eko
Ileegbimọ aṣofin Eko ti fontẹ lu u pe kijọba din owo ifẹyinti ti wọn n san fawọn gomina to ti ṣakoso nipinlẹ Eko ku si idaji, bẹẹ ni wọn wọgi le awọn ẹtọ ati ajẹmọnu kan ti wọn maa n fun wọn.
Nibi ipade akanṣe kan to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni gbọngan apero wọn l’Alausa, Ikẹja, ni wọn ti fẹnu ko lori ọrọ ọhun.
Lasiko ipade naa ni igbimọ alabẹṣekele ile lori ọrọ nipa iṣẹ ọba jabọ iṣẹ tawọn aṣofin naa ti kọkọ yan fun wọn ṣaaju lori ọrọ owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ ọba atawọn oloṣelu kan nipinlẹ Eko, eyi lo mu kawọn aṣofin naa bẹrẹ ijiroro lori abajade ati awọn aba tigbimọ naa dabaa fun ile.
Ninu ijiroro wọn, awọn aṣofin naa fẹnu ko lati wọgi le ofin to wa nilẹ tẹlẹ, ninu eyi ti wọn ti lawọn maa pese ile kan l’Ekoo, ọkan l’Abuja fun awọn gomina ipinlẹ Eko nipari saa iṣakoso wọn.
Bakan naa ni wọn ṣofin pe dipo ọkọ ayọkẹlẹ meji ati ọkọ akero kan fun awọn gomina, eyi ti wọn gbọdọ maa paarọ rẹ lọdun mẹta mẹta, ọkọ ayọkẹlẹ kan ati ọkọ akero kan ni wọn yoo maa pese fun wọn bii ajẹmọnu ifẹyinti wọn, ọdun mẹrin mẹrin si ni wọn yoo maa paarọ awọn ọkọ naa.
Wọn ni bi ayipada yii ṣe kan awọn gomina naa lo kan awọn igbakeji wọn pẹlu, yoo si bẹrẹ iṣẹ gbara ti gomina ba ti buwọ lu u lati sọ ọ dofin lẹkun-un-rẹrẹ.
Lasiko ijiroro naa, awọn aṣofin kan lawọn o fara mọ adinku owo ifẹyinti ati awọn ajẹmọnu wọnyi, wọn ni ipo ọrọ-aje orileede yii mu kawọn nnkan gbowo leri, eyi si ti ṣakoba fun owo tawọn oloṣelu naa n gba, tori ohun ti wọn yoo fowo naa ra ko to tatijọ mọ.
Ṣugbọn Olori ile naa, Mudashiru Ọbasa, ni loootọ ni nnkan ti gbowo lori, sibẹ, awọn o gbọdọ gbagbe pe awọn araalu lawọn n ṣoju fun, ohun tawọn araalu ba si fẹ lo yẹ kawọn ṣiṣẹ le lori. O ni tipẹtipẹ lawọn araalu ti n gba ijọba nimọran lati mu adinku ba owo ti wọn n na lori iṣejọba ati eto iṣakoso.
Yatọ siyẹn, Ọbasa ni idi mi-in ti adinku fi ni lati de ba iye nnkan irinna ti wọn n pese fawọn oloṣelu naa ni pe beeyan ṣe n dagba si i ni nnkan ti yoo maa lo n dinku si i.
Lẹyin ijiroro wọn, wọn buwọ lu awọn abadofin wọnyi, wọn si pinnu lati taari rẹ si ọfiisi gomina ipinlẹ Eko fun ibuwọlu, ki ofin naa le bẹrẹ iṣẹ.