Wọn ti ji ọba alade kan at’iyawo ẹ gbe o

Faith Adebọla

 Gbogbo ẹni to ba fẹẹ ṣe kabiyesi laafin ọba alaye kan, Ọba ilu Idọfin, Shedrack Durojaye Obibeni, tabi ti tọhun n reti pe ki olori rẹ yọju soun, yoo wulẹ pẹ lori idọbalẹ ni, tori lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ, akata awọn ajinigbe kan tẹnikan o ti i mọ ibi ti wọn ti wa, ati inu igbo kijikiji ti wọn wa, ni ọba alade naa atiyawo rẹ ohun wa bayii.

Ba a ṣe gbọ, loju ọna Makutu si Idọfin, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Yagba, nipinlẹ Kogi, niṣẹlẹ aburu naa ti waye nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ta a wa yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, SP William Aya, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ keji, iyẹn Tusidee, ọsẹ yii, sọ pe niṣe lawọn janduku ẹda ti wọn n jiiyan gbe naa fi ibọn da mọto ti kabiyesi ati iyawo rẹ wa ninu rẹ duro, lọgan ti wọn duro ni wọn ti wọ wọn bọọlẹ, ti wọn na ibọn si wọn, bẹẹ ni wọn ṣe ko awọn mejeeji ni papamọra, ti wọn si ji wọn gbe lọ sibi tẹnikan o ti i mọ.

Alukoro naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ti n ṣakitiyan lati doola ẹmi awọn olori ilu yii.

O tun ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, CP Hakeem Adeṣina, ti paṣẹ fawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ abẹ rẹ lati fọn ka sigboro atawọn inu igbo agbegbe tiṣẹlẹ naa ti waye pẹlu erongba lati doola ẹmi ọba alaye yii ati iyawo rẹ lẹsẹkan naa, ki wọn si  fi pampẹ ofin gbe awọn ọyaju ajinigbe ti wọn o bẹru ori ade, ti wọn wa nidii iṣẹlẹ ibanujẹ yii.

Leave a Reply