Faith Adebọla, Eko
Ṣe ẹ ranti iṣẹlẹ ibanujẹ to waye lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, lagbegbe Ijẹṣatẹdo, ni Surulele, nigba ti ọlọpaa kan, Sajẹnti Samuel Philipps, fibọn da ẹmi ọmọleewe ẹni ọdun mejidinlogun kan, Mọnsurat Ojuade, legbodo? Wọn ti gbaṣọ lọrun ọlọpaa yii, ki i ṣe pe wọn gbaṣọ lọrun ẹ nikan ni, wọn le e danu patapata lẹnu iṣẹ ọlọpaa, wọn si lo maa foju bale-ẹjọ laipẹ.
Ba a ṣe gbọ, latigba tiṣẹlẹ naa ti waye ni wọn ti mu Ọgbẹni Philipps, ti wọn fẹsun kan an pe o huwa odoro naa, to yinbọn pa ọmọọlọmọ lai ṣẹ lai ro, wọn si bẹrẹ iwadii abẹle tileeṣẹ ọlọpaa maa n ṣe fawọn oṣiṣẹ wọn to ba lufin, gẹgẹ bii ilana wọn.
Abarebabọ iwadii abẹle ọhun, wọn ni ọlọpaa naa ko jẹ lẹni ti wọn n pe ni agbofinro mọ, iwa rẹ ko si ba tileeṣẹ ọlọpaa mu mọ, eyi ni wọn fi disimiisi ẹ, wọn le e danu loju-ẹsẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Adekunle Ajiṣebutu sọ pe ijiya ẹṣẹ ọlọpaa ọdaran yii ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, tori awọn maa wọ ọ dewaju adajọ laipẹ, ko le fimu kata ofin lori ẹṣẹ nla to da yii.