Wọn ti mu Akpan atọrẹ ẹ ti wọn n ji waya ina tu l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Ole o waye ire, ahamọ ọlọpaa nibi ti wọn ti n tọpinpin iwa ọdaran ni Panti, Yaba, lawọn gende meji kan, Akpan Fortune, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ati ọrẹ ẹ, Stanley Umebuane, ẹni ọdun mẹrinlelogun, wa bayii, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla yii, nilẹ mọ ba wọn nidii iṣẹ adigunjale ti wọn sọ d’iṣẹ aṣela, waya ina ẹlẹntiriiki ni wọn n ji tu n’Ikẹja ati Ikoyi, nipinlẹ Eko.

Aarọ ọjọ Sannde ọhun lọwọ ba Fortune ni tiẹ, Opopona Acme Cresent, ni Agidingbi, Ikẹja, ni wọn ti fura si i, o ti fi irinṣẹ ti wọn fi n ge waya to wa lapo ẹ ge awọn waya ibanisọrọ ati ti gẹnẹratọ awọn ẹni ẹlẹni kan, o n ka awọn waya naa mọra wọn lọwọ lawọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa kọja, ni wọn ba sun mọ ọn lati bii leere ọrọ.

Wọn lọkunrin naa kọkọ ṣe bii ẹni pe oṣiṣẹ ina mọnamọna loun, ṣugbọn nigba ti wọn yẹ ẹ wo daadaa ni wọn ri i pe alọ-kolohun-kigbe ẹda ni, ni wọn ba gbe e janto.

Ọna Gerrard, to wa lagbegbe Ikoyi, l’Erekuṣu Eko lọhun-un, ni Stanley fi ṣe ojuko iṣẹẹbi tiẹ, wọn niṣe lo n palẹ awọn waya tiransifọma wọn mọ, to si n lọọ ta a jẹun. Wọn lọkunrin naa ni jiga ati ṣọbiri to fi maa n hulẹ lati hu waya ina mọnamọna ti wọn ba ri mọlẹ jade.

Ṣa, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ṣe sọ, ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE lori ikanni Wasaapu rẹ lọjọ Aje, Mọnde yii, o lawọn mejeeji ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ, wọn si ti n ṣalaye ara wọn, bẹẹ ni wọn n ba wọn kọ ọ silẹ, tori awọn ẹsibiiti ti wọn ka mọ wọn lọwọ atawọn funra wọn maa dero kootu laipẹ.

Leave a Reply