Wọn ti mu Alao, wọn lo mọ nipa aafaa atọmọ rẹ ti wọn ji gbe n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Majistreeti kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo ti paṣẹ pe ki wọn ju awakọ kan, Sulaiman Alao, sẹwọn fẹsun pe o lọwọ ninu bi wọn ṣe ji ọga rẹ, Aafaa Sọliu ati ọmọ rẹ, Ali, gbe lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, ni nnkan bii oṣu kan sẹyin.

Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara lo wọ afurasi ẹni ọdun mọkandinlaaadọta ọhun, Sulaiman Alao, lọ siwaju ile-ẹjọ pe o lẹbọ lẹru, ọwọ rẹ ko mọ lori bi awọn ajinigbe naa ṣe ya bo ile mọlẹbi aafaa, ti wọn si ni ki iyawo rẹ ko gbogbo ọsọ ara to ni jade, bi bẹẹ kọ, to ba ṣiyan laye, ajule ọrun ni yoo ti lọọ gbọbẹ. Lasiko naa ni ọkan lara awọn ajinigbe ọhun gba aburo aafaa iyẹn Fasasi leti, loun naa ba fibinu gba tiẹ pada. Ibinu eyi laọn ajinigbe fi yinbọn pa a, wọn si tun ji aafaa gbe lọ. Lẹyin naa ni wọn beere fun ọgọrun-un kan miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ.

Agbefọba, Abdullahi Sann, sọ fun kootu pe Alao wa ni ayika ile aafaa lasiko ti awọn ajinigbe n pitu ọwọ wọn, wọn ni ko le sọ idi kan pato to fi wa nibẹ lasiko naa, eyi lo jẹ ki ọn fura si i pe o mọ nipa ijinigbe ọhun, fun idi eyi, ki adajọ pasẹ ki wọn ju u si ahamọ.

Majistreeti Aminat Ọmọtayọ Shittu, naa ko ro o lẹẹmeji to fi ni ki wọn maa gbe Alao lọ sọgba ẹwọn to wa l’Oke-Kura, lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹẹdogun, osu Kejila, ọdun 2022.

Leave a Reply