Wọn ti mu awọn ọmọ Naijiria yii nilẹ Libya

 Adeoye adewale

Mẹta lara awọn ọmọ orileede Naijiria kan ti wọn n gbe niluu Al-Khums, lorileede Libya, ti wọn ko niwee igbeluu gidi lọwọ lọwọ ijọba orileede naa ti tẹ bayii, wọn lawọn maa ba wọn ṣẹjọ gidi lori ọna eru ti wọn gba wọlu awon ati ẹsun ole jija ti wọn fi kan wọn.

ALAROYE gbọ pe ẹsun ole jija ati iwa ọdaran ni wọn fi kan awọn ọmọ orileede Naijiria meji ọhun ati ọmọ orileede Ghana kan ti wọn mu pẹlu wọn.

Wọn ni ṣe lawọn mẹtẹẹta jalẹkun ọgba ibi ti wọn ti n sin ohun osin niluu naa, ti wọn si ji awọn ohun ọsin wọn ko sa lọ kọwọ too pada tẹ wọn laipẹ yii.

Ijọba orileede naa ti ju awọn mẹtẹẹta sahaamọ wọn, wọn ni laipẹ lawọn maa foju wọn bale-ẹjọ lati le jiya ẹṣẹ ti wọn ṣẹ.

Ẹsun meji ọtọọtọ ni wọn fi kan wọn, ẹsun akọkọ ni pe, wọn wọlu awọn wa lai niwee igbeluu lọwọ ati pe wọn tun lọọ jale loko araalu naa.

Leave a Reply