Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Yoruba bọ, wọn ni ọjọ gbogbo ni ti ole, ṣugbọn ọjọ kan ṣoṣo ni ti olohun, owe yii lo ṣẹ mọ ọkunrin ẹni ogoji odun kan, Ọlaoluwa Babatunde, to yan iṣẹ jiji foonu ni awọn ile ijọsin ni Aiyegbaju -Ekiti atawọn ilu miiran to wa lagbegbe ìjọba ibilẹ Ọyẹ, nipinlẹ Ekiti lara.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abùtù, ṣalaye pe ọdaran naa to maa n da nikan rin, ni awọn ọlọpa ti n wa lati ọjọ pipẹ sẹyin nitori awọn ẹsun ti wọn ti gbọ nipa rẹ pe o maa n ji foonu ko ni awọn ile ijọsin gbogbo. O ni niṣe ni ọdaran ọhun maa n lọ lati ṣọọṣi kan si ekeji, ti yoo si ṣe bii pe olujọsin ni oun naa. Nigba to ba ri i pe isin ti wọ awọn eeyan lara ni yoo maa yọ foonu wọn lọ lọkọọkan.
O ni ọwọ palaba ọdaran ọhun ṣegi ni kete to ji foonu ti ko din ni meje, to jẹ ti awọn olujọsin ijọ Christ Apostolic Church, to wa ni Aiyegbaju -Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ.
Alukoro awọn ọlọpa yii sọ pe lasiko ti wọn n fi ọrọ wa ọdaran naa lẹnu wo, o jẹwọ pe oun nikan ni oun maa n da ṣe ọsẹ naa, ati pe agbegbe Aiyegbaju ati Ọyẹ-Ekiti, loun ti maa n wọ ile ijọsin, ti oun maa n ji ẹrọ ilewọ wọn.
Bakan naa lo tun jẹwọ pe foonu ti oun ti ji ni ile ijọsin Ijọ Irapada (Redeemed Christian Church), ati eyi ti wọn n pe New Reality Christian Center, to wa ni Ọyẹ-Ekiti ko niye.
Ninu itọpinpin awọn ọlọpaa ni wọn ti mọ pe ọrẹ ọmọkunrin yii to wa niluu Eko lo maa n ko foonu naa ranṣẹ si lati ba a ta a, tiyẹn yoo si fi owo to ba kan an ranṣẹ pada si i.
Meje lara awọn foonu to ji ni ile ijọsin Christ Apostelic Church, Aiyegbaju-Ekiti, ni awọn ọlọpaa ti gba pada lọwọ rẹ, bẹẹ ni wọn ti ranṣẹ pe awọn olujọsin ijọ naa ti wọn ni ẹrọ ilewọ yii lati waa tọka si eyi to ba jẹ tiwọn.
Abutu sọ pe ọdaran naa ti wa ni atimọle awọn ọlọpaa, bakan naa ni wọn ṣi n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ lori ọrọ naa. O fi kun un pe ọdaran naa yoo foju ba ile-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ naa.