Wọn ti mu Bobo Chicago, ọmọ Naijiria to n ṣe gbaju-ẹ niluu oyinbo 

Adewale adeoye

Odu ni Oluyọmi Ọmọbọlanle Bombata, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, tawọn eeyan mọ si Bobo Chicago, ki i ṣẹ aimọ fun oloko, nitori nawo nawo ati ọmọ jayejaye ni. Ṣugbọn ọpọ ni ko mọ pe awodi jẹun epe sanra lo n fi ọrọ naa ṣe pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn eeyan lo n pa lẹkun to fi n ri awọn owo to n na.

Ọdọ awọn ọlọpaa agbaye ta a mọ si (FBI) to wa lagbegbe Illinois, niluu Chicago, lorileede Amẹrika, ni afurasi ọdaran naa wa bayii to ti n ṣalaye ẹnu rẹ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o n ṣe Yahoo ni Illinois ati Oklahoma, lorileede Amerika, o si ti lu awọn eeyan ilu naa ni jibiti obitibiti owo dọla ko too di pe ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii.

ALAROYE gbọ pe ogunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lọwọ tẹ Bobo Chicago, lẹyin to sa kuro lagbegbe Oklahoma to n gbe tẹlẹ, nigba tawọn agbofinro agbegbe naa n wa a. Ko pẹ rara to de Illinois, niluu Chicago, ni wọn fọwọ ofin mu un ju sahaamọ.

O kere tan, o ti lu awọn araalu naa ni jibiti miliọnu mẹta din diẹ ($2.8m) owo dọla.

Awọn ara Oklahoma, to lu ni jibiti owo nla naa ni wọn lọọ fẹjọ rẹ sun awọn agbofinro, awọn yẹn ṣewadii nipa rẹ, wọn si ri i pe loootọ lo n nawo bii ẹlẹda laarin ilu.

Ijọba ilu naa ṣalaye pe akaunti awọn ileeṣẹ aladaani ati tijọba ni afurasi ọdaran naa maa n doju kọ, ti yoo si fi ọgbọn jibiti gba ọpọlọpọ owo dọla jade nibẹ. Ileetaja igbalode kan ti wọn ti n ta oriṣiiriṣii ọti waini lo maa n dari awọn owo to ba ji si, ti yoo si lọọ gba a to ba to asiko to fẹẹ lo o.

Wọn ti pada fọwọ ofin mu awọn alaṣẹ ileetaja igbalode naa pe wọn n ran Bobo Chicago lọwọ ninu iwa ọdaran to n hu. Bakan naa ni wọn tun ti ri ọkan lara awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ ọdaran naa mu.

Ijọba Amerika ti lawọn maa ṣewadi nipa afurasi ọdaran naa daadaa, tawọn si maa foju rẹ bale-ẹjọ tiwadii tawọn n ṣe ba ti tẹnu bọpo.

Leave a Reply