Wọn ti mu Emmanuel to fipa ba obinrin laṣepọ lẹyin to ja a lole tan n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ba a ṣe n kọ iroyin yii, atimọle ọlọpaa ni ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun (22) kan, Kẹhinde Emmanuel, ogboju afurasi ole pẹlu meji ninu awọn ẹmẹwa ẹ, Abdullahi Oseni ati Hassan Musa, wa. Ẹsun idigunjale lo sọ wọn dero atimọle.

Ara ọtọ ni ti Emmanuel ninu ọran yii nitori oun lolori ikọ adigunjale naa, oun naa si ni wọn lo fipa ba ọmọbinrin kan laṣepọ mọnu ile wọn lẹyin to ja onitọhun lole owo ati ẹrọ ibanisọrọ rẹ tan.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Emmanuel nikan lo lọọ ja idile Akingbọla (ta a fi ojulowo orukọ wọn bo wọn laṣiiri) lole laduugbo Apata, to si fipa ba ọmọbinrin wọn laṣepọ. Olojule mẹfa ni ile naa, awọn to n gbebẹ ko si ranti tilẹkun ti gbogbo wọn fi sun lọ.

Jagunlabi taari ilẹkun kekere abawọnu ọgba ile naa, o ri i pe wọn ko ti i, o si wọnu ile lọ. Yara kan to tun ri i pe wọn ṣi silẹ lo wọ lọ taara, to si ko ẹrọ ibanisọrọ mẹrẹẹrin to wa ninu yara naa.

Lẹyin to ko awọn foonu ọhun tan to fẹẹ tilẹkun lo gburoo pe ẹnikan ti taji ninu awọn onile ọhun to n sun lọwọ. O pe ọmọbinrin naa sita, o si fipa ba a laṣepọ lori aga ninu ọgba ile wọn nibẹ.

Ṣugbọn ọmọkunrin yii sọ pe oun ko ba obinrin ẹni ogun (20) ọdun naa laṣepọ, oun kan fẹnu ko o lẹnu lasan ni, ṣugbọn ki oun ma purọ, oun tun fọwọ tẹ ẹ lọyan ki oun too sa jade ninu ile naa.

Ninu foonu mẹrin to ji, o ta mẹta nibẹ, ọkan lẹgbẹrun meje Naira, ekeji lẹgbẹrun mẹsan-an Naira, nigba to ta ẹkẹta lẹgbẹrun-un mẹẹẹdogun Naira (15,000), o si n lo eyi to daa ju nibẹ funra rẹ.

Foonu onifoonu to n lo yii la gbọ pe awọn agbofinro lo lati wa a nipa imọ ijinlẹ.

Nigba to de aaye kan, o fura pe wọn ti n lo ẹrọ ibanisọrọ naa lati maa fi tọpinpin oun kiri, o ba kuku ta iyẹn naa danu nitakuta. Ẹgbẹrun mọkanlelogun Naira (N21,000) lo ta a foonu to to ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150,000) ọhun. Bẹẹ lo bẹrẹ si i ṣa kiri ki ọwọ awọn agbofinro ma baa tẹ ẹ.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa fi han an pe ko sibi ti oju Ọlọrun ko to, ati pe ẹgbẹrun Samuẹli ko le sa mọ Ọlọrun lọwọ.

Bo ṣe kuro nibi iṣẹ lọjọ naa, kaka ko gba ile lọ taara, ọdọ ọrẹbinrin ẹ lo gba lọ gẹgẹ bii iṣe ẹ latigba to ti bẹrẹ si i sa fawọn agbofinro. Ṣugbọn nibi ti oun pẹlu ololufẹ rẹ yii ti n rinrin alarede wọn lọ lawọn ọlọpaa ti yọ si wọn lojiji, ti wọn si fi panpẹ ofin gbe jagun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, fidi eyi mulẹ, o ni ni nnkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii, ni jagunlabi pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ ṣiṣẹ ibi naa laduugbo Apata, n’Ibadan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn ọbayejẹ eeyan ti wọn dihamọra pẹlu ibọn, aake atawọn nnkan ija oloro mi-in wọnyi ni wọn fibọn gba ẹrọ kọmputa alaagbeletan, foonu, owo atawọn nnkan mi-in lọwọ ọkunrin kan laduugbo Apata, n’Ibadan.

”Afi bii ẹni pe eyi ti wọn fipa gba lọwọ ọkunrin naa ko to, niṣe ni wọn tun lọọ ji foonu ati owo ko ninu ile mi-in, ti wọn si tun ba ọkan ninu awọn obinrin to n gbenu ile naa laṣepọ.

“Ni kete ti wọn fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wa to wa laduugbo Apata, lawọn agbofinro teṣan naa ti bẹrẹ iwadii loju-ẹsẹ. Iwadii ọhun lo seeso rere ti wọn fi ri Emmanuel to jẹ olori ikọ awọn afurasi adigunjale yii mu.

“Lẹyin to ti jẹwọ ẹsun ta a fi kan an tan, to si darukọ awọn meji to maa n ra awọn ẹru ẹlẹru ti wọn ba ji ko fawọn ọlọpaa ni wọn lọọ mu awọn mejeeji ọhun torukọ wọn n jẹ Abdullahi Oseni, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (33) ati Hassan Musa, ti oun je ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28).

“Ṣugbọn nigba ti ọwọ yoo fi ba wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn (27), Emmanuel tun ti ko awọn ọmoogun rẹ lọọ ka baba kan to n jẹ Ọgbẹni Joseph mọle ẹ nitosi NNPC, laduugbo Apata kan naa mọle, ti wọn si ja a lole foonu atowo ẹ to ko pamọ sinu ile.

“Foonu mẹjọ, kọmputa agbeletan meji pẹlu ọbẹ ati aake la ba lọwọ wọn’’.

Gẹgẹ bii iwadii akọroyin wa, ọmọ bibi ilu Iganna, nipinlẹ Ọyọ, ni Emmanuel, ṣugbọn adugbo Ọmi-Adio, n’Ibadan, lo n gbe. Awọn obi ẹ ti kọra wọn silẹ, iya wọn si da ọmọ mẹtẹẹta to da wọn pọ silẹ fun baba wọn nigba ti gbogbo wọn ṣi wa ni kekere.

Awijare ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun yii ni pe ebi lo sun oun dedii ole jija, ṣugbọn o jọ pe ole jija ti wa ninu ẹjẹ rẹ ni, paapaa, pẹlu bo ṣe jẹ pe bo ba ji nnkan oni nnkan tan, aṣọ ati nnkan ọṣọ ara lo saaba maa fowo ọhun ra.

ALAROYE gbọ pe ole naa ni Emmanuel ja n’Iganna, niluu wọn lọhun-un to fi sa wa s’Ibadan lọdun 2019. Niṣe lo deede wọ inu ṣọọbu kan ti wọn ti n ṣaaji foonu lọ, to si ji odidi ẹrọ ibanisọrọ mẹfa ko lọjọ naa.

Ni kete ti iwadii awọn agbofinro ba ti pari lori iṣẹlẹ yii ni wọn yoo gbe afurasi adigunjale yii atawọn to n ra nnkan oni nnkan lọwọ wọn lọ si kootu.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DP Ọṣinfẹṣọ, lo fidi eyi mulẹ nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdaran naa fawọn oniroyin n’Ibadan.

 

Leave a Reply