Wọn ti mu Mariam, apẹrẹ tomato lo lọọ ji l’Ọja Kulende, n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun, bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fun iyaale ile kan to lọ sinu ọja kan ti wọn n pe ni Kulende, niluu Ilọrin, bii ẹni to fẹẹ raja nibẹ lọjọ ọja, to si ji apẹrẹ tomato ati ata gbe nibẹ.

Niṣe ni inu awọn eeyan ọja naa n dun ṣinkun nigba ti ọwọ tẹ obinrin yii, nitori wọn ti maa n pariwo ni gbogbo igba pe awọn eeyan kan maa n wọnu ọja naa ti wọn maa n gbe awọn ni nnkan.

Akolo ajọ sifu difẹnsi, ẹka ipinlẹ Kwara, ni Mariam, ẹni ọdun mejilelọgbọn, naa wa bayii. Ohun to tori ẹ dero ọdọ awọn amunifọba naa ko ju ti apẹrẹ tomato ati Ata to lọọ ji ni ọja Kúléndé, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin (South), Ilọrin, nipinlẹ Kwara lọ.

Ninu atẹjade ti Alukoro ajọ naa, Ayẹni Ọlasunkanmi, fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti salaye pe lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lọwọ tẹ Mariam, nibi to ti lọọ ji apẹrẹ tomato ati ata lọja to gbajumọ naa.

Ayẹni ni o pẹ tawọn olutaja ninu ọja naa ti maa n mu ẹsun ole wa si ọfiisi awọn, ti iwa ole jija yii si n dija silẹ laarin awọn ọlọja ẹlẹgbẹ wọn ko too di pe ọwọ ba Mariam nibi to ti lọọ ji apẹrẹ tomato ati Ata gbe.

O fi kun un pe Mariam jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun ole ti wọn fi kan oun. O ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii lafurasi naa yoo foju ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply