Faith Adebọla, Ogun
Ẹni ọdun mọkanlelogun pere ni Ismaila Ibrahim, oun lọjọ-ori ẹ kere ju lọ ninu awọn afurasi ọdaran mẹrin kan tọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ tẹ, iṣẹ ajinigbe lawọn olubi ẹda naa n ṣe, inu igbo nla kan to wa lagbegbe Ibara-Orile, ni wọn fi ṣe ibuba wọn, ibẹ ni wọn lugọ si ti wọn ti n da awọn eeyan lọna, ti wọn n ji wọn gbe gbowo nla, ṣugbọn ọwọ palaba wọn ti segi.
Orukọ awọn yooku ni Musa Muhammed, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Ọkanlawọn Muhammed, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ati ẹni to dagba ju laarin wọn, Irekura Abu, ẹni ọdun mẹtalelogoji.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ f’ALAROYE l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla yii pe, latari bi iṣẹlẹ ijinigbe ati akọlu ṣe n waye lemọlemọ, paapaa lagbegbe Soyọọye ati Ibara-Orile, o lo ti fẹẹ dojoojumọ tawọn araalu n waa fẹjọ sun ni teṣan pe awọn ajinigbe n han wọn leemọ lagbegbe ọhun. Eyi lo mu ki Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, paṣẹ fawọn ọtẹlẹmuyẹ lẹka ti wọn ti n gbogun ti iwa ijinigbe pe ki wọn wọnu igbo tọ awọn amookunṣika ẹda naa, ki wọn si wa wọn lawaari nibi yoowu ti wọn fi ṣe ibuba wọn.
SP Taiwo Ọpadiran lo lewaju ikọ awọn ọlọpaa ọhun, iwadii ijinlẹ ati ifimufinlẹ ti wọn ṣe lo jẹ ki wọn ri Irukura Abu mu, o jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun loun n ko nnkan ija oloro tawọn ajinigbe n lo fun wọn, o loun ki i jiiyan gbe ni toun, ṣugbọn ti wọn ba nilo ibọn ati ẹtu, oun loun n ba wọn wa a, toun yoo si jẹ ko tẹ wọn lọwọ.
Mimu ti wọn mu Abu yii lo jẹ kiṣẹ awọn ọlọpaa naa ya, wọn lo ran awọn lọwọ lati ri ẹni keji, Musa Muhammed, mu. Bo ṣe n jade bọ lati ibuba wọn laṣaalẹ ọjọ kan, o fẹẹ waa ra ounjẹ fawọn ti wọn ji gbe, ti wọn so mọlẹ bii ẹran sahaamọ wọn, ati ounjẹ tawọn ajinigbe ẹlẹgbẹ rẹ yoo jẹ, nigboro.
Iwadii ti wọn ṣe fawọn mejeeji yii lo taṣiiri pe awọn ajinigbe ọhun lo ji Biṣọọbu Joṣua Ọladimeji gbe ni ṣọọṣi Agọ Adua, Prayer City, to wa ni Keesan, Abẹokuta, lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.
Bakan naa ni wọn jẹwọ pe awọn lawọn ji Abilekọ Kafayat Jẹlili gbe laduugbo Ogo Tuntun, niluu Ibara-Orile, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, kan naa.
Awodi to n re’Bara, ti ẹfuufu ta a nidii pẹẹ, o lohun to ba ya kan ko gbọdọ tun pẹ mọ, awọn mejeeji tọwọ tẹ yii ti mu ki’ṣẹ awọn ọtẹlẹmuyẹ naa ya, wọn jẹwọ bi wọn ṣe maa ri awọn yooku wọn, lọwọ ba tẹ Ismaila Ibrahim ati Ọkanlawọn Muhammed.
Lara nnkan ija ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ibọn oloju meji kan, ati ibọn kan. Wọn tun ba ọpọlọpọ oogun abẹnu gọngọ ati ọta ibọn rẹpẹtẹ nikaawọ wọn.
Bankọle ti paṣẹ kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ ṣewadii to lọọrin lori iṣẹlẹ yii, o lawọn o ni i jafara lati foju awọn apamọlẹkun-jaye naa bale-ẹjọ tiwadii ba ti pari.
Bakan naa lo ni awọn o ni i dawọ duro lati ṣawari awọn ajinigbe atawọn janduku to fi igbo agbegbe naa boju lati maa da omi alaafia ilu to wa layiika naa ru.