Monisọla Saka
Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti lọ siluu oyinbo ti wọn ri ohun mu wale, bi wọn ṣe n ran ẹbi lọwọ ni wọn n ran ọrẹ ati ojulumọ lọwọ, eyi ko sẹyin bi wọn ṣe kọju mọ ohun ti wọn ba lọ sọhun-un, ti wọn si ranti ọmọ ẹni ti wọn n ṣe.
Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ fun ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) kan, Saheed Azeez, ọmọ Naijiria to gbọna ti ko tọ lọ siluu Oyinbo yii, ti ko si tun ran oun to ba lọ sọhun, to jẹ pe jibiti lo n lu nibẹ. Pakute ti mu ọmọkunrin naa lọwọ o, awọn ọlọpaa orileede UK ti gbe e janto, afaimọ ni yoo si tun foju kan awọn ara ọrẹ ati ibatan to fi silẹ si Naijiria ko too gba ilu oyinbo lọ.
Abẹwo ni irufẹ fisa ti Azeez ba wọ orilẹ-ede UK, ṣugbọn nigba to debẹ lo ta ku, ti ko pada sile mọ titi ti iwe naa fi lejọ mọ ọn lọwo.
Awawi to n ṣe nigba ti asiko ile too lọ, ti ko si fẹẹ lọ, ni pe awọn ọkunrin ti wọn maa n lajọṣepọ pẹlu ọkunrin ẹgbẹ wọn loun, nitori eyi lawọn alakatakiti kan fi n dọdẹ ẹmi oun, ti wọn fẹẹ pa oun, oun ko si ni i fẹ kawọn ikọ Boko Haram to wa ni Naijiria pa oun ti oun ba pada lọ sile.
Eyi ni ijọba ilu naa ro ti wọn fi da a duro si orileede naa, ti wọn si pese aabo fun Azeez, ṣugbọn ọmọkunrin yii ko mọ’wọn ara ẹ rara.
Obinrin mẹta ọtọọtọ ni wọn ni ọkunrin to ti sọ fawọn oyinbo pe ọkunrin ẹgbẹ oun loun maa n ba lo pọ yii fun loyun, lo ba ṣegbeyawo pẹlu ọkan ninu wọn, eyi to ta ko ofin ti wọn fi gba a, to si tun lodi si ilana igbeyawo lọdọ tiwọn. Yatọ si eyi, jibiti ni wọn ni ọmọkunrin naa n lu awọn eeyan lọ rai lorileede naa, to si fi iwa jibiti naa ko ọpọlọpọ owo jọ.
ALAROYE gbọ pe laarin bii ọdun kan ati oṣu meji ti Azeez debẹ lo ti da ileeṣẹ ti wọn ti n luuyan ni jibiti kalẹ lọhun-un, to si ri i daju pe ọwọ ẹ kan ọwọ pẹlu awọn ọdaran mi-in to n ba a ṣiṣẹ. Oriṣiiriṣii adirẹsi ile awọn eeyan lo si fi n gba awọn ọja ti ko sanwo ẹ lori ẹrọ ayelujara.
Oniruuru awọn nnkan to ra lori ikanni ayelujara ti wọn ti n taja bii Ebay ati Facebook ni wọn ni Azeez ti maa n gba ọja, ti yoo si ta a ni ṣọọbu ọmọ iya ẹ kan to n ta awọn eroja to n lo ina lagbegbe Wigan, lorilẹ-ede England.
O kere tan, awọn eeyan to n lọ bii ọọdunrun, ni wọn ni ọkunrin yii ti fi gbaju-ẹ tan lati ta awọn tokunbọ ohun eelo to n lo ina, foonu, kamẹra atawọn nnkan mi-in fun un lai sanwo fun wọn.
Gbogbo ere ti wọn ba ri lori ọja kọọkan yii lo maa n ti ọbẹ bọ, ti yoo fi owo kọinsi ori ayelujara ti wọn n pe ni bitcoin san an fawọn agbodegba rẹ gbogbo.
Wọn ni akiyesi bi ẹru loriṣiiriṣii ṣe maa n de si agbegbe North Manchester, nibi ti Azeez n gbe, ti awọn ọlọpaa ṣe ni wọn ṣe tọpinpin rẹ, ti wọn si wa a kan. Lasiko to n gbe ọmọ rẹ lọ sileewe lọwọ tẹ ẹ, nibi to ti n gbiyanju lati tọju awọn foonu mẹta kan to fi n lu jibiti pamọ sinu baagi ọmọ ẹ.
Bakan naa ni iwadii fi han pe akanti banki to n lọ bii mẹtadinlogoji loun nikan n lo pẹlu oriṣii orukọ bii mẹfa.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi ẹ mulẹ, ọkan lara awọn oṣiṣẹ kootu to n jẹ Andy Evans, ṣalaye pe, foonu ti wọn ri gba gan-an lo tu aṣiri gbogbo iwa jibiti ori ayelujara ti Azeez n hu, ati gbogbo ọja to n ra lai sanwo.
Pẹlu bi ọwọ awọn agbofinro ti tẹ Azeez, laipẹ yii ni wọn ni wọn yoo foju ẹ bale-ẹjọ. Yẹkinni kan ko si le yẹ ẹ, fọpa wọn ni ẹwọn rẹ, iyẹn ti ko ba jẹ ẹwọn gbere.