Monisọla Saka
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, ti tẹ Bitrus Gyang, ogbologboo afurasi to n rọ ibọn, to si n ta ibọn lọna aitọ.
Lasiko tawọn agbofinro n ṣe paturoolu nibi biriiji ilu Buruku, lọwọ tẹ afurasi yii lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii. Ibọn nla AK-47 bii ogun ni wọn ka mọ ọn lọwọ.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, ASP Mansir Hassan, ni ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa lọwọ tẹ ẹ. Ẹyin mọto Golf alawọ dudu, ni ọkunrin to wa lati ijọba ibilẹ Barkin Ladi, nipinlẹ Plateau, yii tọju awọn ibọn loniran-n-ran naa si.
Lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo ni afurasi yii jẹwọ pe ki a rọ ibọn ta ni iṣẹ ti oun yan laayo, ati pe ko din ni ẹẹmẹta toun ti ko iru awọn ibọn bayii rin-irinajo lọọ ta fawọn onibaara oun.
Hassan fi kun ọrọ rẹ pe niwọn igba ti Gyang ti fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro, to si n ran wọn lọwọ lori iwadii, iṣẹ ti n lọ lori b’ọwọ yoo ṣe tẹ awọn ẹmẹwa rẹ.