Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ wọn ti tẹ ọdọ langba mẹrinla nipinlẹ naa pẹlu ẹsun pe wọn n fi ayederu iṣẹ lu awọn eeyan ni jibiti.
Lakooko ti wọn n ṣe afihan awọn ọdaran naa ni olu ileeṣẹ wọn to wa loju ọna Ikẹrẹ-Ekiti, niluu Ado-Ekiti, ọga agba awọn sifu difẹnsi ipinlẹ naa, Ọgbẹni Sunday Agboọla, sọ pe ẹka kogberegbe ajọ naa ni wọn ṣawari awọn ọdaran naa ti wọn yan iṣẹ fifi ọgbọn jibiti gba owo lọwọ awọn eeyan pẹlu ẹtan pe wọn yoo ba iru ẹní bẹẹ wa iṣẹ lu wọn ni jibiti.
O ṣalaye pe awọn ọdaran naa ni wọn ko awọn eeyan kan pamọ sinu ile kan ni Ado-Ekiti, ti wọn si n gba owo ribiribi lọwọ wọn pẹlu ileri pe awọn yoo pese iṣẹ fun wọn.
Lakooko ti ALAROYE n fọrọ wa wọn lẹnu wo, ọkan lara awọn ti wọn ti lu ni jibiti naa, Favour Ayala, sọ pe lati ilu Ogbomọṣọ ni oun ti wa si Ado-Ekiti lati waa wa iṣẹ pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ kan ti orukọ rẹ njẹ “Quest Company” lẹyin ti ẹnikan to jẹ alarina wọn lori ẹrọ Fesibuuku (Facebook) sọ nipa ileeṣẹ naa fun oun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun fi ẹda iwe-ẹri oun ranṣẹ sileeṣẹ naa lẹyin ti oun san ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (N70,000) gẹgẹ bii owo ile ti oun maa gbe lakooko ifọrọ-wa-ni-lẹnu-wo, ki oun too bẹrẹ iṣẹ naa.
O ṣalaye pe lakooko ifọrọ-wa-ni-lẹnu-wo ti wọn ṣe fun wọn ni Ado-Ekiti, awọn ọdaran naa ko gba awọn laye lati ba ẹnìkankan sọrọ ni gbogbo ayika ibi ti wọn ti ṣe eto naa.
Eyi lohun to sọ fun akọroyin wa. “Mo wa lati ilu Ogbomọṣọ si Ado-Ekiti, Mo ba ọrẹ kan pade lori ẹrọ ibanidọrẹẹ Fesibuku, mo si beere iṣẹ to n ṣe, o si sọ fun mi pe oun n ṣiṣẹ nileeeṣẹ aladaani kan ti wọn maa n ba eeyan wa iṣẹ, ti wọn si tun n gba eeyan siṣẹ, ti orukọ rẹ njẹ “Quest Company. ”
“Lẹyin ti mo fi iwe-ẹri ati kaadi idanimọ mi (NIN) ati foto pelebe ranṣẹ si wọn tan, wọn pe mi lẹyin ọjọ keji pe wọn ti gba gbogbo iwe-ẹri mi ti mo ko silẹ wọle. Lẹyin ti mo pada lọ si olu ileeṣẹ naa ni mo ri i pe onijibiti ni wọn.
“Mo ti san owo to to bii ẹgbẹrun lọna aadọta Naira fun wọn. Wọn ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira ni wọn maa fi gbe faili silẹ, ti wọn si tun ni ki n san ẹgbẹrun lọna aadọta miiran gẹgẹ owo ile ti ma a gbe lasiko ifọrọ-wa-ni-lẹnu-wo. Akoko yii ni mo waa rii pe onijibiti ni awọn eeyan wọnyí. Wọn ko gba ki gbogbo awa ta a wa sibẹ ba ara wa sọrọ. ”
Lara awọn ọdaran naa sọ pe oun eelo ati ẹṣọ ile ni wọn n ta, bakan naa ni ileeṣẹ wọn miiran wa ni Oke-Ọya, nigba ti olu ileeṣẹ wọn miiran wa ni ilu Eko.
Wọn ni awọn maa n ta awọn ohun eelo ti wọn fi n ṣe ẹṣọ ile, ati oogun iwosan fun awọn oriṣiiriṣii aisan. Bakan naa ni wọn ni awọn maa n ṣe idanilẹkọọ fun awọn eeyan ati iforukọsilẹ fun ileeṣẹ, ti wọn si ni ileeṣẹ awọn wa ni orilẹ-ede Malaysia, Singapore, Thailand ati Philippine. Wọn ni ilu Eko ni ọga agba ileeṣẹ awọn wa. Bo si tilẹ jẹ pe wọn ko ti i fun ẹnikẹni niṣẹ, sibẹ, wọn ti gba ẹgbẹrun lọna ogun Naira lọwọ ẹnikọọkan awọn to ko si wọn lọwọ.
O ni ‘’Ori ẹrọ Fesibuuku la ti pade awọn eeyan, ṣugbọn nigba ti a de si ipinlẹ Ekiti a ṣalaye iru iṣẹ ti a n ṣe fun awọn eeyan ka too maa gbowo lọwọ wọn.”