Wọn ti mu Yusuf, lẹyin to ṣa ọmọkunrin kan ladaa lo gba foonu ẹ to si sa lọ

Monisọla Saka

Ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Yusuf Ajibade, ti dero atimọle bayii lẹyin to fi ada gba foonu lọwọ ọmọdẹkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan lagbegbe Okerube, Ikọtun, nipinlẹ Eko.

Afurasi ọhun to ti n ka boroboro latimọle awọn ọlọpaa sọ pe loootọ loun dena de ọmọdekunrin naa, toun si bẹ ẹ ni ada nigba tọmọ yẹn ko fẹẹ fi foonu rẹ silẹ lẹrọ. O fi kun un pe lalẹ ọjọ toun jale foonu ọhun naa loun ta a fẹnikan to n re kọja lọ lọjọ ọhun kan naa.

O ni, “Lagbegbe Okerube Bus Stop, ni mo duro si lalẹ ọjọ naa pẹlu ada mi lọwọ nigba ti ọmọ yẹn n kọja lọ. Mo ni ko fi foonu rẹ le mi lọwọ, ṣugbọn o kọ jalẹ, o si bẹrẹ si i pariwo. Bi mo ṣe ṣa a ni ada niyẹn. Ẹgbẹrun mẹwaa Naira (10,000) ni mo ta foonu yẹn fọkunrin kan lalẹ ọjọ naa”.

Foonu ti Ajibade fi ada gba lọwọ ọmọkunrin ọhun, to si ta a nitakuta, ni wọn lo to ẹgbẹrun lọna ọgọrin (80,000) Naira.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn foju ọdaran naa bale-ẹjọ Majisireeti Yaba, nipinlẹ Eko.

Ọga ọlọpaa to jẹ agbefọba ni kootu, Thomas Nurudeen, ṣalaye pe lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni afurasi ti jale ti wọn fi fẹsun kan an yii, ati pe ẹsun ti wọn fi kan an yii ta ko abala kẹtadinlọọọdunrun iwe ofin ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015.

Adajọ P. R. Nwaka ni ki wọn fi afurasi si ahamọ, lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun yii.

Leave a Reply