Faith Adebọla, Eko
Ileegbimọ aṣofin agba ilẹ wa ti paṣẹ fawọn ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa, iyẹn awọn kọsitọọmu, pe ki wọn da awọn irẹsi atawọn ọja ọlọja ti wọn lọọ fọwọ agbara ko ninu ṣọọbu wọn n’Ibadan pada lai fakoko ṣofo, wọn niwa ti wọn hu naa ko bofin mu rara, aṣilo agbara ni.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni igbimọ alabẹ ṣekele lori ọrọ ilana ati anfaani (Ethics and Privileges) tile aṣofin agba l’Abuja (Senate) fẹnu ko lori ipinnu wọn, wọn lodi si iwa awọn kọsitọọmu naa. Wọn ni ki Ọga agba pata fun ileeṣẹ aṣobode, Hammed Ali, ẹni ti igbakeji rẹ, Ọgbẹni Garba Mohammed, ṣoju fun nibi apero naa, ṣeto lati da gbogbo awọn ọja ti wọn ko ọhun pada fawọn oniṣowo ti wọn ni in.
Wọn ni ọsẹ meji pere lawọn fun wọn lati ṣe bẹẹ, awọn o si fẹ ki ijokoo mi-in tun waye latari pe wọn kuna lati mu aṣẹ naa ṣẹ.
Yatọ si dida ẹru wọn pada, wọn tun paṣẹ fawọn kọsitọọmu naa pe ki wọn lọọ yọ awọn agadagodo ti wọn fi ti ṣọọbu awọn oniṣowo naa pa kuro, ki wọn si mu ontẹ ati iwe ti wọn lẹ mọ awọn ilẹkun wọn kuro.
Wọn tun ni wọn gbọdọ da gbogbo owo eyikeyii ti wọn ba ti gba lọwọ awọn oniṣowo naa pada, tori owo ti ko bofin mu ni.
Igbimọ naa ni o han kedere pe igbesẹ tawọn aṣọbode naa gbe ta ko ofin ileeṣẹ kọsitọọmu, ko si ba ilana iṣiṣẹ wọn mu, wọn niwa naa tun ta ko ofin orileede wa.
Wọn ni ofin tawọn kọsitọọmu naa gun le ti wọn fi huwa ti wọn hu yii ni ofin ti Aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, buwọ lu lọdun 2007, ṣugbọn ohun to wa ninu ofin naa ni pe awọn kọsitọọmu laṣẹ lati gbẹsẹ le ẹru fayawọ eyikeyii to ba wa ni nnkan bii kilomita ogoji yipo ẹnubode ilẹ wa, ki i ṣe ẹru to wa ninu ṣọọbu awọn oniṣowo ti wọn n ta, tabi to wa nibi to jinna ju ogoji kilomita si ẹnubode.
Sẹnetọ Ayọ Akinyẹlurẹ to jẹ alaga igbimọ alabẹ ṣekele naa ran ijokoo leti pe iru iwa tawọn kọsitọọmu hu yii ti waye ri lọdun diẹ sẹyin nipinlẹ Katsina, o ni tori ẹ lawọn aṣofin asiko naa ṣe yọ ọga kọsitọọmu to ṣaaju ikọ ọhun nigba yẹn danu bii ẹni yọ jiga.
Bakan naa ni Sẹnetọ Kọla Balogun to n ṣoju ẹkun idibo apapọ Guusu Ọyọ sọ pe “Yatọ si pe kawọn kọsitọọmu da ọja ti wọn ko pada, o lo pọn dandan ki wọn tọrọ aforiji lọwọ awọn ọlọja ati awọn ọmọ Naijiria fun iwa aṣilo agbara ati itapa sofin ti wọn hu naa.
Kọla ni: “Ofin sọ pe ẹ laṣẹ lati ti ṣọọbu oniṣowo pa niṣoju oniṣọọbu naa, ofin ko sọ pe kẹ ẹ maa lọọ ja ṣọọbu oniṣọọbu lọganjọ oru ti wọn o si nibẹ. Tori naa, ko si bi Ọbọ ṣe ṣori t’Inaki o ṣe, ti wọn ba le da ọja awọn oniṣowo pada ni Katsina, ki wọn yaa da ti Ibadan yii pada ni, ọja naa si gbọdọ pe perepere.”
Amọ ṣa, igbakeji ọga agba kọsitọọmu, Garba Mohammed, sọ awijare tiẹ nibi ijokoo naa, o ni ki i ṣe pe awọn kan fẹẹ gba ounjẹ lẹnu awọn oniṣowo tabi awọn fẹẹ f’ọla j’iyọ, o ni iṣẹ iwadii lawọn ṣẹ de’bẹ tawọn fi mọ nipa awọn ọja ofin tawọn onifayawọ n ko pamọ sawọn ṣọọbu ọhun, o ni eeyan to loootọ ni ọga agba awọn, ọwọ rẹ si mọ nidii iṣẹ yii.
Garba lawọn lẹtọọ labẹ ofin lati fọ ferese tabi ilẹkun wọle ti idi to fẹsẹ rinlẹ ba wa lati ṣe bẹẹ. O loun o mọ nipa iṣẹlẹ ti Katsina ti wọn mẹnuba yii, ṣugbọn oun ko le fọwọ sọya pe wọn maa da awọn ọja naa pada, ki wọn jẹ koun lọọ jiṣẹ fun ọga agba awọn.
Lori ọrọ yii, bakan naa, Babalọja gbogbogboo fun ipinlẹ Ọyọ, Alaaji Sumaila Aderẹmi Jimọh, ti parọwa fawọn oniṣowo lati ma ṣe fun ẹnikẹni ni owo riba tabi ki wọn gbọna ẹburu yanju iṣoro to delẹ yii. O ni ẹsẹ ofin tawọn maa fi yanju ọrọ ọhun lawọn ti gun le yii, o si da oun loju didun lọsan yoo so nigbẹyin.
Tẹ o ba gbagbe, lati bii ọsẹ meji sẹyin ni wọn ti fẹsun kan awọn ẹṣọ aṣọbode, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ati Abuja, pe wọn foru boju lọọ ja ṣọọbu awọn oniṣowo kan ninu Ọja Ọba ati Bodija, wọn ko ọpọlọpọ irẹsi ati ororo, wọn si fi agadagodo ati ontẹ wọn tilẹkun awọn ṣọọbu naa pa.
Ọpọlọpọ ariwo ati awuyewuye lo ṣẹlẹ lẹyin iṣẹlẹ yii, eyi lo si mu ki awọn iwe ẹsun rọjo ṣọdọ sẹnetọ to n ṣoju agbegbe ọhun, ati gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde.