Adewale Adeoye
Awọn agba bọ wọn ni ẹgbẹrun Saamu kan ko le sa mọ Ọlọrun Ọba lọwọ, bẹẹ gan-an lo ri pẹlu bi ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Borno ṣe pada tẹ ọdaran kan, Ọgbẹni Abubarkar Muhammad, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, to jẹ ogbologboo ẹlẹwọn to sa lọgba ẹwọn Maiduguri, nipinlẹ Borno, lasiko iṣẹlẹ omiyale to waye niluu naa laipẹ yii.
ALAROYE gbọ pe o le lawọn ẹlẹwọn ọọdunrun ti wọn sa mọ awọn wọda lọwọ ninu ọgba ẹwọn ti wọn wa lasiko iṣẹlẹ omiyale to waye niluu naa laipẹ yii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Ahmed Mohamed Wakil, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe ọwọ ti pada tẹ Abubarkar, ogbologboo ẹlẹwọn kan to sa mọ awọn wọda lọwọ ninu ọgba ẹwọn Maiduguri.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘Lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni nnkan bii aago mẹta ọsan, ni araalu kan to n gbe ni Wọọdu Bulakara, nijọba ibilẹ Gubio, foju kan Abubarkar Muhammad tawọn wọda n wa lagbegbe rẹ, o n rin gberegbere kaakiri aarin ilu naa ni. Onitọhun lo sare pe awọn ọlọpaa lori foonu, ti wọn si waa fọwọ ofin mu un lọ sọdọ wọn.
Alukoro ni awọn maa too da ọdaran naa pada sọdọ awọn wọda, ki wọn le ju u sọgba ẹwọn to wa tẹl
ẹ pada
.