Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn ọmọ bibi ilu Igbajọ, nijọba ibilẹ Boluwaduro, nipinlẹ Ọṣun, ti figbe bọnu pe awọn ko ri gbogbo awọn ade iṣembaye ati awọn ọpa aṣẹ ilu naa mọ bayii.
Awọn eeyan naa ti wọn ṣewọde wa si Oṣogbo, kilọ fun Gomina Adegboyega Oyetọla lati ma ṣe fọwọ si erongba awọn mọdaru kan lati fi agidi yan alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọọba Gboyega Famọdun, gẹgẹ bii Ọwa ti ilu Igbajọ.
Oniruuru akọle ni wọn gbe lọwọ, lara nnkan ti wọn kọ sibẹ ni pe “Ijọba ipinlẹ Ọṣun, ẹ ma ṣe fi agidi yan alaga ẹgbẹ APC bii Ọwa Igbajọ”, “Baba Famọdun lo jẹ ni ijẹta, ko ti i kan an”, “Ẹ faaye gba ile-ẹjọ lati sọrọ lori ẹni to kan lati jẹ Ọwa”, “Gbolẹru kọ lo kan lati jẹ Ọwa Igbajọ” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Oloye Aderẹmi Adeifẹ kilọ pe ilu naa ko ni i faaye gba fifi ọwa ọla gba awọn loju. O ni awọn ọmọ ilu naa ti hu u gbọ nipa ipinnu awọn kan lati kede Ọwa Igbajọ tuntun lai fi ti ẹjọ to wa ni kootu ṣe.
Bakan naa ni ọmọọba kan lati ile Akẹran, niluu Igbajọ, Gbenga Akande, ṣalaye pe akoyawọ lawọn fẹ ninu yiyan ọba tuntun, o kilọ pe ki awọn oloṣelu ma da alaafia ilu naa ru.
O sọ siwaju pe ile Looye ni wọn maa n ko awọn ade iṣẹmbaye atawọn ọpa aṣẹ ọba to ba waja si, ṣugbọn latigba ti Ọwa Faṣade ti waja ni wọn ko ti ri awọn nnkan naa mọ.
O ni dipo ki wọn ko wọn lọ si ile Looye, ṣe ni awọn agbaagba kan ko wọn lọ siluu Oṣogbo. O ni ko sẹni to ri esi gidi kan fun oun latigba ti oun ti n beere pe bawo ni awọn ade naa ṣe rin.
Ọmọọba Akande fi kun ọrọ rẹ pe ilu Igbajọ tobi ju ẹnikẹni lọ, ohun gbogbo ti onikaluku si n ṣe wa ninu itan.