Adewale Adeoye
Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọwọ, ahamọ awọn agbofinro orileede Libya, lọhun-un ni ọmọ Naijiria kan tawọn ọlọpaa ko darukọ rẹ, nitori ti iwadii ṣi n lọ lọwọ nipa ohun to ṣe wa bayii, o n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn.
ALAROYE gbọ pe ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan an. Wọn ni o la haama mọ ọrẹ korikosun rẹ kan lori lasiko ti wọn n ja nitori ọrọ ti ko to nnkan, ti onitọhun si ku loju-ẹsẹ.
Ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni iṣẹlẹ ibanujẹ naa waye lagbegbe Sabha, lorileede Libya, nibi tawọn ọrẹ mejeeji naa n gbe. Awọn araalu naa ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ko kọbi ara si i pe ọrọ tawọn ọrẹ mejeeji naa n sọ lọjọ yii le pada di nnkan nla, ti ẹmi ọkan ninu wọn si maa pada ba a lọ.
Lojiji ni afurasi ọdaran naa la haama ọwọ rẹ mọ ọrẹ rẹ lori, tiyẹn si ṣubu lulẹ gbalaja, to si n pọkaka iku. Awọn araale ibi ti wọn n gbe lo gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn ọmọkunrin naa ti ku ki wọn too gbe e de ọsibitu.
Lẹyin ti afurasi ọdaran naa ri i pe ọrẹ oun ti ku lo ti fẹẹ sa lọ, ṣugbọn wọn gba a mu, wọn si fa a le awọn ọlọpaa agbegbe naa lọwọ lati baa ṣẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Awọn ọlọpaa sọ pe iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.