Faith Adebọla
Binu obi awọn ọmọleewe kan ṣe n dun, ti wọn n ki ara wọn ku ewu bii aja to re’le ẹkun to bọ, bẹẹ lawọn obi mi-in n wa ẹkun mu nipinlẹ Kaduna lọjọ Ẹti, Furaidee, latari pe awọn ọmọ wọn ṣi wa ninu igbekun awọn janduku agbebọn, wọn o tu wọn silẹ.
Ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ yii, lawọn afẹmiṣofo naa yọnda mejidinlọgbọn ninu awọn ọmọleewe Bethel Baptist to wa lagbegbe ijọba ibilẹ Chikun, nipinlẹ Kaduna, lẹyin ti wọn ti wa nigbekun wọn fun ọjọ mejilelaaadọta gbako.
Taara ni wọn ko awọn ọmọ naa lọ sileewe ọhun, nibi ti wọn ti ni kawọn obi wọn wọn waa pade ọmọ kaluku.
Tẹkun-tomije lawọn obi naa fi n ki awọn ọmọ wọn kaabọ, bi wọn ṣe n dupẹ pe iku aitọjọ re awọn ọmọ naa kete, bẹẹ ni wọn n kẹdun latari ohun tawọn majeṣin wọnyi foju wina rẹ lakata awọn agbebọn laarin oṣu meji o di ọsẹ kan ti wọn ti wa nibẹ.
Ọjọ karun-un, oṣu keje, ọdun yii, lawọn agbebọn naa ya bo ileewe awọn ọmọ naa, ti wọn si fipa ji okanlelọgọfa (121) gbe sa lọ ninu wọn. Wọn fi mejidinlọgbọn lara awọn ọmọ naa silẹ lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, lẹyin ti wọn ti gba owo rẹpẹtẹ lọwọ awọn obi wọn
Wọn tun da awọn mẹẹẹdogun mi-in silẹ lọsẹ to kọja, ko too kan awọn ti wọn ṣẹṣẹ fi silẹ yii.
ALAROYE gbọ pe niṣe lawọn kan lara awọn obi awọn ọmọleewe naa lọọ ta ilẹ, oko ati ile wọn ki wọn le rowo tawọn ajinigbe naa n beere fun san tori ọmọ wọn, bẹẹ lawọn obi ti agbara wọn ko gbe e lati san owo itusilẹ bu sẹkun tori wọn lawọn o mọ’na abayọ si riri ọmọ tiwọn naa gba pada.