Faith Adebọla
Awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ ijọba apapọ, DSS, ti tun fi meji ninu awọn ọmọọṣẹ Sunday Igboho mẹrin ti wọn ṣẹku sahaamọ wọn silẹ. Orukọ awọn meji ọhun ni Tajudeen Irinloye ati Uthman Opẹyẹmi Adelabu.
Ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn mejeeji dẹni ominira lẹyin ti lọọya to ṣoju fun wọn nile-ẹjọ, Amofin Pẹlumi Ọlajẹngbesi, tun pada sọfiisi awọn DSS ọhun lati gba awọn mẹrin ti wọn ṣẹku, silẹ.
Pẹlu bi wọn ṣe tun fi awọn meji silẹ yii, aropọ awọn ọmọọṣẹ Sunday Igboho ti wọn tu silẹ lahaamọ di mẹwaa, awọn meji to ṣẹku ni Amudat Habibat Babatunde ati Jamiu Noah Oyetunji.
Ṣaaju ni wọn ti tu awọn mẹjọ silẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọgbọnjọ, oṣu kẹjọ, to kọja, latari bile-ẹjọ ṣe paṣẹ pe ki wọn gba beeli awọn afurasi ọdaran ti wọn fẹsun kan naa.
Ṣugbọn Ọlajengbesi ti leri pe awọn yoo pe ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lẹjọ ti wọn ba kọ lati fi awọn meji to ṣẹku silẹ. O lawọn ti pari gbogbo eto to yẹ lori awọn afurasi mejila naa, ko si sidii gunmọ kan ti awọn DSS fi taku lati tu wọn silẹ ju wọn fẹẹ lo ọwọ agbara lori wọn lọ.
“Bawọn DSS ṣe n ṣe aṣayan to wu wọn lori aṣẹ ile-ẹjọ, ti wọn pa idaji mọ kọyin si idaji yii ko bojumu, titasẹ agẹrẹ si ile-ẹjọ lo jẹ, ko si yẹ ki iru aṣa yii waye labẹ ijọba awa-ara-wa, niṣe lo tumọ si pe ajọ DSS ko kunju oṣuwọn
Labẹ ofin, DSS ko lagbara lati sọ pe eyi to ba wu awọn ninu aṣẹ ile-ẹjọ lawọn maa pamọ, tawọn si maa kọyin si eyi ti ko ba rọgbọ fun wọn.
Bọrọ ṣe ri yii, a fẹ ki gbogbo aye mọ pe to ba fi maa di ọjọ Aje, Mọnde, to n bọ yii, ti wọn o ba ti i fi awọn meji to ku silẹ, a maa pe ileeṣẹ DSS lẹjọ si kootun ni.
Agbofinro lo yẹ kawọn ẹṣọ DSS jẹ, iwa titẹ ofin loju, fifari apa kan da ọkan si ti wọn n hu yii lewu fun DSS.” Bẹẹ l’Ọlajẹngbesi fesi.