Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Eeyan mẹrin mi-in tun ti bọ sọwọ awọn ajinigbe labule Olubọ, loju ọna Ayetoro-Ilara, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ipinle Ogun.
Nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu karun-un yii niṣẹlẹ naa waye. Mọto ayọkẹlẹToyoya Avensis ti nọmba ẹ jẹ FFF 654 TK lawọn ti wọn ji gbe naa wa, bi wọn ṣe n lọ lawọn agbebọn naa kọ lu wọn lojiji, ti wọn ko eeyan mẹrin wọgbo lọ ninu wọn.
Awọn obinrin meji kan ti ori ko yọ lọwọ awọn ajinigbe yii, Iswat Akeugbẹru ati Rọfiat Ọladẹinde, ṣalaye pe mẹrin ni awọn agbebọn to yọ sawọn lojiji yii, wọn ni niṣe ni wọn bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ bi wọn ṣe da mọto awọn duro.
Iswat ati Rọfiat sọ pe wọn gba foonu atowo to wa lọwọ awọn ki wọn too ko awọn mẹrin wọgbo lọ. Wọn tẹsiwaju pe dẹrẹba to wa mọto naa pẹlu awọn obinrin mẹta tawọn jọ wa ninu ọkọ ni wọn ko wọgbo lọ.
Bakan naa ni wọn ṣalaye pe awọn ajinigbe ọhun fi Fulani ati Hausa kan tawọn jọ wa ninu mọto naa silẹ, wọn ko ji wọn gbe. Wọn ni wọn kan n nawọ sawọn to wu wọn lati gbe lọ ni, wọn si ko wọn wọgbo lọ lalẹ naa.
Iṣẹlẹ yii toju su awọn eeyan agbegbe Olubọ, Imẹkọ-Afọn, Idi-Ẹmi ati Ilara, to bẹẹ to jẹ wọn jade ṣewọde l’Ọjọruu, ọjọ karun-un, oṣu yii(, wọn lawọn ko ni i gba ki ijinigbe maa ṣe bayii waye laduugbo awọn.
Ẹ oo ranti pe ko ti i pe ọsẹ kan ti wọn ji obinrin kan ti wọn pe ni Roselyn Edusi, gbe lagbegbe Ọfada, ti ẹnikẹni ko si ti i ri i titi dasiko yii.
Awọn ọlọpaa ti gbọ nipa ijinigbe to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ yii, koda, lgbakeji kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ yii, Muritala Bọlanle, ti de ibi ti wọn ti ji awọn eeyan naa gbe, o si lawọn ti bẹrẹ si i wa awọn ajinigbe ọhun. O ni ọwọ yoo ba wọn laipẹ, awọn yoo si gba awọn ti wọn ji gbe kalẹ lọwọ wọn.